Bi eniyan ba n wa ojulowo iroyin ti ko labula, ẹ ma je n tan yin,
awon iroyin bẹẹ ko si lori telifisan tabi rẹdio mọ. Bẹẹ si ni ẹ ko le ri i loju
iwe iroyin ojoojumọ.
Ori ayelujara lo wa. Bi eniyan ba n fẹ iroyin oju ẹsẹ,
awon iroyin yii ko si lori ibi kankan mo yato si ori ayelujara.
Otitọ ọrọ bi isokuso ni i ri.
Pupọ awon iroyin ori redio, telifisan ati iwe iroyin lo je awon
iroyin ti won ti jọ bi elubọ. Pupo awon nnkan to se ara loore ni won yoo ti jọ
danu latari ibẹru ati awon ofin kan-anpa ti ajọ ti ijoba gbekalẹ ti n se alaboju
won se fun awon ile ise iroyin.
Se won ni ko si bi irunmu alagbaro se gun to, ẹni gbe ise fun
lọga rẹ. Sẹ ẹ mọ wi pe awon ijoba ni won fun won ni iwe asẹ lati sise.
Awon nnkan won yii si mu ki adinku agbara de ba awon ile ise
iroyin eleyii ti awon eniyan ti gbara le gege bi orisun lati mo ohun to n sẹlẹ
lawujọ.
Ohun to tun bọ ja irawo won ko ju olaju ati ero igbalode to
wole de lọ.
Mi o so wi pe ojulowo ile ise
iroyin ko si, sugbon pupo won ni won ko le se bi won se fẹ.
Pelu ipo ti awon ile ise iroyin
wa, njẹ awa le gba wi pe eni sise nibe nikan loniroyin gidi? Iro nla to jina si
otito ni.
Bi o tilẹ je wi pe aimoye sawo-sogberi naa ni won wa kaakiri,
sibesisbe, ise iroyin sise lai si ibẹru tabi ase abẹnilori maa niyi loju awon
eniyan awujo.
Omoyele Sowore ti n sisẹ iroyin rẹ bọ ọjọ ti pẹ. Orisii agbekalẹ isẹ
iroyin rẹ lo je wi pe yoo soro fun ile ise iroyin kankan lati gba wole lai se
wi pe won bu omi laa nipa agbekala awon ofin won.
Pupo ninu awon ilana yii lo
si je ohun ti ko le ba Sowore lara mu. Sugbon nipa agbara imo ero eleyii ti
olaju gbe wole.
Omoyele Sowore dagbo
gbe bẹẹ lo si daraba nla ti won bo loni bi oosa akunlebo. Omoyele Sowore yii ni alase Sahara Repoters.
Mo si n tesiwaju...
0 comments:
Post a Comment