Hon Akeem Adeniyi Adeyemi (Skimeh) |
Ka bini nile ọla ko ni ka rinrin iyi
lawujọ. Aimọye ori-ade ni won ti sọmọluabi nu dẹni yẹyẹ lawujo nitori ijẹkujẹ.
Sugbon sa, ti Sango ba n pa araba ti n fa igi iroko ya, bi tigi nla kọ.
Ọmọọba Alaafin Oyo, Akeem Adeyemi ti jẹwo
ara rẹ lagbo oselu gẹgẹ bi ojulowo ọmọluabi ti ko gbagbe ile ọla to ti jade wa.
O ti se alaga ibilẹ ri, ko jeun japo saya. Okiki otito inu ati ifẹ ọmọniyan ti fi n sisẹ lọwọlọwọ nile igbimọ asoju-sofin
Abuja ti di mimọ fun gbogbo aye.
Nitooto, a-ji-sebi-Oyo-laari, Oyo tia ko ni
sebi ẹnibọọdi laelae.
Skimeh, Femi Gbajabiamila ati Alaafin Oyo |
Akeem Adeniyi Adeyemi jẹ onirẹlẹ eniyan, kosi
ibeere ti won le bi nipa isẹ ilu to gbe dani ti ki i dahun. Gbogbo igba lo si
ma n jabọ ibi to ba isẹ de fun awon ara ilu ti won ran nise.
Ki n ma paro tan yin, oko Temitope jomiloju
gidi.
Skimeh ati iyawo re, Yeye Temitope Famadewa Adeyemi |
Hon Akeem Adeyemi ti gbogbo eniyan tun mo
si Skimeh pe eni ogoji odun (40yrs) lonii (8-12-16).
Adura mi ni wi pe Edumare yoo tun bo fun ni
ọgbọn, imọ, ẹmi ifinsin, ibẹru Oluwa lati le tesiwaju ninu gbigbi ọgọ Naijiria
ga gẹgẹ bi asoju rere ile Yoruba.
#HAppyBirthdaySkimeh #Akinkanju
#EniyanPataki Gominalọla
0 comments:
Post a Comment