Seun Egbegbe lagbo ariya |
Ode ariya ni won ti gburo Seun
Egbegbe lọsẹ to koja eleyii to fi han gbangba wi pe, o ti pada de lati ilu
Malaysia.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Seun Egbegbe
gbera lo si ilu Malaysia leyin ti ile ejo sun igbẹjọ rẹ di ọjọ kẹjọ osu kejiodun 2017 ta a wa yii.
Aimoye awon eniyan ni won si n
ro wi pe maanu naa fi ọgbọn salọ ni, ati wi pe, o seese ko farasoko siluu
Malaysia raurau.
Lara awon eniyan ti won tako bi
won se gba ki ọkunrin naa ri irin-ajo jade ni Naija ni Kemi Omololu-Olunloyo. Ninu
ọrọ Kemi Olunloyo lo ti naka abuku si awon olopaa Naijiria gẹgẹ bi awon
agbofinro ti ko mọse won nise.
Ninu akojopo iroyin OlayemiOniroyin Agbaye nipa ohun ti awon eniyan n so kaakiri ayelujara, awon kan so wi
pe, isẹlẹ naa seese ko jẹ isẹ aye tabi ki gbajumo naa fi soogun okiki.
Awon kan si
tun so wi pe misiteeki lasan lo sẹlẹ lọjọ naa, alaye won naa ni wi pe, gbajumo naa
koja ẹni to le lọ soja lati lọ ji foonu. Ohun ti won gbiyanju lati sọ naa ni wi pe, Seun Egbegbe ki i se eniyan yẹpẹrẹ
Sugbon Sa, ọjọ kẹjọ osu keji (8-2-2017) ti
fẹ ẹ wole de. Ti ọjọ naa ba de, iru idajọ wo ni won fẹ da fun ololufee Toyin
Abraham (Eni ti n jẹ Toyin Aimakhu tẹlẹ) nigba kan ri?
0 comments:
Post a Comment