Ohun to
daju ni wi pe, èrò ti eniyan dimu fun ìgbà pipẹ nipa igbe aye rẹ ma n pada wa
si imusẹ. Ijamba nla ni fun ọ lati sọ ireti nu ninu ara rẹ. Awon eniyan tilẹ le
pe ọ ni oniranu lonii, sugbọn ma so ala rẹ nu nipa ọjọ ọla rẹ. Bakan naa, si ni
igbagbọ ninu ara rẹ.
Èrò ti
eniyan ba dimu ninu ọkan rẹ fun igba pipẹ, dandan ni ki iru èrò bẹẹ wa simusẹ.
Ibẹrẹ rẹ le kere, o sile ma jọ aye loju, fi ireti sinu ọla pẹlu igbagbọ to le
koko bi oju ẹja.
Ma kaarẹ,
si ma rẹwẹsi, tesiwaju ninu àlá rẹ to dimu ninu ọkan rẹ.
Èrò ti
eniyan ba dimu ninu ọkan rẹ fun ìgbà pípẹ́, a maa pada sẹ mọ́ni lara. Sebi ẹ mọ
wi pe ti ewe ba pẹ lara ọṣẹ, n se ni i pada dọṣẹ.
Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Ilu Naija olokiki si ni ilu mi, ilu to n san
fun wara ati oyin. Ilu awon ọlọpọlọ pipe ati omoluabi eniyan. Ki Oluwa ko bukun
ilu mi, Naijiria ilu ogo. Amin
0 comments:
Post a Comment