"Ti Yoruba ba ni EKURO ni alabaku EWA" Kini itunmo ohun ti won so? Kilode ti won fi n lo EKURO ati EWA papo? #YorubaDun #Ojuloge
Idahun Awon eniyan lati inu Yoruba Dun:
Peter Adewale: Idi ti a fi nlo Ekuro ati ewa papo ninu Ewa ede Yoruba ni wipe... Lara ekuro ni ati mu adin ekuro jade eyiti a maa nlo lati fi para ti osi maa n mu ki oju dan ati pe o maa n busi ewa eniyan.
Ekuro je nkan ti a maa n ri lati ara Ope nigba ti a ba ti yo awon eroja iyoku bi epo pupa tan, pi pa ni a maa n pa ekuro ki a to yo jade kuro ni inu ibi to a se lojo si....
Adeyemi Ayodeji Samuel: otu mo si wipe ko si oya kan to le yawa, won ma nlo owe oto na larin ololufe meji ti o tumo si wipe won ko ni fi arawon sile laye.
Peter Adewale: Since beauty in Yoruba is ewa and ekuro is used to make the oil that can increase one's ewa, the Yoruba's would say ekuro no alabakun ewa. Alabakun means adds to or increase
Mosobalaje Olusola: Ni ara Ekuro ni 'ADI' (a local cream) ti jade ohun ni oje ipara ni igba na, osi maa nbu ewa (beauty) kun eni ti oba ti fi para , idi ni yi won fi npaa lowe pe ekuro ni alabaku ewa , i.e the ekuro (palm kanel) that produced Adi (a local cream) is the main secret of beauty (EWA)

Jaiyeoba Funmilola: O tumo si pe eniyan oko ati aya ko si ohun to le ya wön afi iku
Oduntan Modupe: Bi o ti se ye emi si ni pe kokoro lalabaku ewa nitori pe ko si bi ewa se le wa ti ko ni ni kokoro ninu. Ko si nnkan ti o da ekuro ati ewa po. Nipa idi eyi ife ti o wa laarin kokoro ati ewa po to bee je ti ko si ohun ti o le ya won.
Onibonokuta Adeola Afolabi: Itumo meji otooto ni mo RI ninu idahun ti awon eniyan ko. Sugbon oye mi PE ewa to wa ninu gbolohun yii ki Se (ewa - beans -do-do) Bi ko SE (Ewa -beauty re- do) ko si ajosepo larin epuro ATI ewa . Sugbon bi awon to salaye PE adin ta RI ninu epuro lo bukun ewa SE so lo jeki o ye mi daradara. Ti ko ba si ami Lori Oro Yoruba, o le so itumo Oro Miran nu . Fun apere (igba, re- re ) 200(igba do- mi) garden egg.
Kilo Fe? Igba ni mo Fe. Elomiran le tumo gbolohun yi si- I want garden egg, ki elomiran si ni - I need two hundred.
Folake Edematie: Ki i se ekuro tabi ewa, asi so Yoruba gbaa ni, sugbon Yoruba ijinle a ma a ni okuro (do do mi) ni alaba baku ewa. Okuro mi kokoro ewa, ko si bi ewa ba ti ni kokoro ki i tan ninu ewa asepo ni toun tewa ni yoo jo Jina papo. Idi niyi ti awon Yoruba fi ma n wi pe okuro ni alabaku ewa. Ki i se ekuro.
0 comments:
Post a Comment