Smiley face

Ero mi nipa Ife Saheed Balogun ati Fathia Balogun

Ayajo awon ololufe nbo lona. Adura mi ni wi pe, awon idile ti ife won ti ku, ki Oluwa so di otun.

Emi gege bi enikan, o ma n je ohun Ibanuje lati ri awon ololufe meji ti won pada di ota ara won eleyii ti won ko ni fe imi ara won ri laatan. Ibanuje nla ni.

Ki i se laaarin awon amuludun wa nikan ni isele yii ti n waye, bose wa ni Liki lo wa ni Gbanja.

Ti ba n so nipa igbeyawo, ko si eni to pe tabi eni to mo julo.

Sugbon, o se pataki ki a se suuru ki a si maa gbadura si Olorun.

Aimoye igbeyawo lo je wi pe ko ba ma baje koja atunse, to ba je wi pe won ko rojo won faye tabi fun ebi kankan.

Asise wa lowo okunrin, asise si wa lowo obirin; ko si eni to pe. Sugbon o da mi loju wi pe, ife Olorun ko ni ki jigi maa tuka.

Mo si gbadura itura fun awon idile ti won la isoro koja ni akoko yii.

Ohun kan ni mo sakiye re, Fathia Balogun si n fi oruka igbeyawo re sowo di ojo oni.

Kosi si iroyin kan nipa wi pe omobirin naa ti n fe oko mii tabi wi pe o ni i lokan lati ni oko tuntun.

Eleekeji, omobirin naa si n je Balogun di akoko yii.

Ni awon igba kan seyin, Saheed leri lati gbe lo si ile ejo nipa bi omobirin naa se n lo oruko re leyin ti igbeyawo won tuka.

Igba ti wahala naa po lo mu omobirin naa maa lo oruko baba re, Williams, nigba naa. Nibayii, Fathia ti n lo Williams papo mo Balogun.

Pelu gbogbo awon apere yii, o si seese ki ife si wa pelu Fathia, odo Saheed ni ko ye wa.

Ni awon akoko ti laasigbo yii n waye, ti awon eniyan n gbiyanju lati pari re, Saheed yii kan naa lo n so wi pe oun ko se mo.

Gege bi mo ti so saaju, ko si eni ti ko ni asise tie, kosi eni to pe, ko si eni to moo se nipa oro igbeyawo.

Bakan naa ni mi o di ebi ru enikeni. Sugbon idunnu mi ni yoo je ti ife ba ri aye joko laaarin awon mejeeji.

Olayemi Oniroyin ni oruko mi, e ba mi kilo fun awon to n pe mi ni Yemi My Lover.

E so fun won pe emi ki i se dokita Ife, ise iroyin nise mi.

E ku ikale.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment