Smiley face

Iwadii nipa Seun Egbegbe: Se ise aye ni tabi amutorunwa?

Ise iroyin je ise kan to je ise elege eleyii to si jinle. Aimoye isori lo pinsi ni ibamu pelu igbokegbodo awon omo eda.

Idi ni yii ti a fi ni awon oniroyin ere idaraya, amuludun, oselu, isunna owo, ilera, irinajo-afe abbl.

Lati sise iroyin to munadoko, ni awon kan fi yan orisii isori kan laayo, eleyii to je ohun to dara pupo ninu ise iroyin aye ode oni.

Bi a se pin ise iroyin sise si isori bee naa ni orisii ti won pin si tayo meji.

Sugbon maa gbiyanju lati so nipa meji tabi meta to romo orisii alaye ti mo fe menuba labe koko oro mi.

Gbogbo ise iroyin lo je mo iwadii ati itopinpin, sugbon orisii ise iroyin olotelemuye tabi asewadi je orisii iroyin kan ti ise re tun gbomimu.

Yato si wi pe orisii ise iwadii yii lekenka, o tun je ohun to lewu yala fun oniroyin tabi ise iroyin re.

O lewu fun oniroyin nitori wi pe, o le kandin ninu iyo ni akoko ti n sise iroyin re.

Bakan naa, ise iroyin le ja le e lori ti okodoro iroyin to gbe dani ba jasi ofege tabi ailesenile nigba to ba jade.

Orisii ise Iroyin yii lo so Seun Oloketuyi, olootu NaijaHottestGist, di ero kirikiri lai ro tele lodun 2015.

Ise iroyin olotelemuye ko fi be e wopo mo nitori kosi koriya ati aabo to peye fun ise iroyin.

Apere ise Iroyin olotelemuye ni iroyin to jade ni awon akoko kan seyin, nipa omo ile igbimo asofin agba, Salisu Buhari, nipa ayederu sabuke to ni oun gba ni ilu Toronto, Canada.

Ile ise iroyin TELL Magazine ni won sise iwadii naa, won si gbe e saye wi pe, iro ni Salisu Buhari pa. Ni iberepepe, Salisu n leri wi pe oun yoo gbe won lo si ile ejo.

Sugbon leyinoreyin, jagunlabi pada tuuba to si kowe fi ipo re sile.

Pupo ninu awon ise Kola Olawuyi lo gunle iroyin olotelemuye, ki Edumare fi orun ke oga oniroyin to file saso bora.

Orisii ise iroyin to tun sun mo olotelemuye ni "Iroyin afoye gbe". Orisii iroyin yii roju die si olotelemuye.

Orisii iroyin yii maa n fi oye gbe awon isele to romo koko iroyin eleyii ti yoo fun wa loye ohun to seese ko je otito.

Bi o tile je wi pe ohun naa ni iwadii ninu, sugbon ko to ti iroyin olotelemuye.

Laaarin ise iroyin olotelemuye ati afoye gbe, abajade won tun je ohun kan pataki to ye ka menu ba.

Iroyin oletelemuye maa n so pato bi oro naa ti ri tabi bo se lo.

Enikan le sise nipa iku to pa Bola Ige ko si so fun wa nipato nipa eni to seku pa agba oloselu naa.

Sugbon iroyin afoye gbe ki i so pato, leyin akojopo awon ise iroyin re to kojo, iyoku wa lowo ara ilu lati wi pe, Lagbaja bayii nitooto lo se bayii.

Ka so wi pe enikan sise iroyin afoye gbe nipa iku Bola Ige, eni naa le se alaye nipa awon alaye to le fi oju okodoro oro han fun araye, lai daruko enikan nipato to sise ibi naa.

Oloselu kan wa nipinle Osun ti opolopo gba wi pe oun lo pa Bola Ige.

Ko si iroyin kankan to soju abe niko, sugbon nipa akojopo iroyin afoye gbe to jade, awon ara ilu gba laisiye meji wi pe, eni naa lo pa Bola Ige.

Lopo igba, awon oniroyin a maa sise iroyin olotelemuye to daju sugbon ti won yoo gbe jade bi ise iroyin afoye gbe latari wi pe, ko si aabo to peye fun onise iroyin.

Sugbon sa, nigba mii, awon ayederu oniroyin a ma sise iroyin arumoje eleyii ti won yoo gbe jade gege abajade ise iroyin oletelemuye lati ba eniyan loruko je leyin ti won ti gba abetele tabi lati fi ta ise iroyin won.

Sugbon gege bi mo ti so ni awon igba kan wi pe, oniroyin ko yato si babalawo.

Babalawo to ba n paro, Ifa won ni i pon laso, oniroyin to ba n seke, iroyin won naa ni i so won di oniyeye lawujo.

Ibi ti mo n lo ko jina, ibi ti mo n ya lo gun bi owo aso.

E pada mi loju keji fun alaye mi nipa Seun Egbegbe, gbajumo ti won furasi wi pe o n fewo.

#Rere run o!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment