Ilu Naijiria ti a n gbe lonii ti kun fun iwa ibaje, idaran, ati ajebanu, nibi ti awon adari ati alagbara ko ranti enikeni mo ju ara won lo.
Sugbon sa, ninu ikoko dudu, eko funfun a ma tibe jade wa. Ko ye ka gbagbe awon akoni ti won fi emi otito sise ilu nigba ti won wa laye. Ko ye ka gbagbe eni fi gbogbo ojo aye re wa ilera mekunnu.
E ma gbagbe Dora Nkem Akunyili, oludari National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC) tile Nigeria nigba kan ri ni.
E so fun iran ti n bo nipa obirin bi okunrin.
E je ki won ko sinu itan wi pe akikanji ni i se.
E si ma se gbagbe wi pe olododo laaarin awon ika eniyan ti ki i beru ni kofeso ti wa.
Sun re oo Arabirin Dora Akunyili (14 July 1954 – 7 June 2014)
0 comments:
Post a Comment