Sir Shina Peters |
Eniyan ti yoo pegan oosa
ni o ni afin o fin to. Terin ba n lo nigbo, tigbo tiju ni i mola erin.
Papalantoro loni ireke, Ijebu loni ikokore, eni ba fe je iyan're yoo delu
Ekiti. Nibi iyan ti n yoruku ninu odo gbe n joni lowo faifai. Ti a ba n so ni
pa orisi agbekale orin ti n je Afro-Juju, gbogbo aye lo mo wi pe Sir Shina
Peter ni oludasile Afro-juju ni ile Africa.
Ipinle Ogun ni won bi Olushina
Akanbi Peters si ni ogbon ojo osu karun-un
odun 1958. Iwadii si fi ye ni wi pe nnkan bi omo odun meje (7) ni Akanbi ti bere
si ife han si orin. Ati igba yii lo naa lo si ti n ko nipa awon ohun elo orin
bi duuru.
Sir Shina darapo mo Ebenezer
Obey gege bi okan lara awon omo leyin re. Igba to kuro leyin obey lo darapo mo
General Prince Adekunle gege bi onijita.
Kaakiria awon ile itura
ati awon aye igbafe si ni egbe orin Adekunle ti n korin ni ilu Eko ni awon
akoko ti Shina wa leyin re gege bi onijita ara.
Ni awon akoko ti Shina
Peter wa leyin Prince Adekunle bi onijita, iwadii fi ye wa wi pe ni awon igba
ti ara Prince Adekunle ko ba mokun to lati sere, Sir Shina Peters lo ma n
lewaju ere gege bi akorin egbe orin naa. Gbogbo awon eniyan ni won si maa n kan
saara si Shina Peters fun awon orin adidun to maa jabo lenu re nigbagbo. Sebi
baa ti waye laari, laari. Ohun ti Edua oke ba si fi ronilorun, bi idan ni i ri
lowo eni.
Sugbon nigba to ya, Shina
Peters fi Prince Adekunle sile lati lo da egbe orin ti won pe ni Shina Adewale
sile. Egbe orin Shina Adewale yii lo je egbe orin ti Sir Shina Peter ati Segun
Adewale da sile. Awon meeji naa ni won si jo n korin papo gege bi olorin ajumo
ko.
Aimoye awo awo orin naa ni
egbe orin Shina Adewale, to je apapo Shina Peters ati Segun Adewale, gbe jade,
ko to wa di wi pe onikaluku sawo re lotooto.
Sir Shina Peters da egbe
orin tie sile eleyii to pe ni Sir Shina Peters and his international stars.
Ni odun 1989, Sir Shina
Peters and his international stars gbe awo orin won akoko won jade eleyii ti
won pe ni Ace (Afro juju series 1).
Igba meji otooto ni awo
orin yii fi gun akaso kini ninu awon awo orin to ta julo laye igba naa eleyii
ti aye si n fe.
Orisi orin Shina Peter ti
won pe ni Afro-Juju yii lo je ojulowo orin juju eleyii to ni ata suesue
Afrobeat ninu. Ilu Afro-juju si yara gbera nile kanmokanmo ju ilu orin juju
lasan lo. Ogbon atinuda orin tuntun yii je itewogba kaakiri laarin gbogbo eya,
asa ati ilu pata. Sir Shina Peters, baba Oluwagbemileke, a maa ta jiata ninu
orin re, fere ko gbeyin ninu orin ti won pe ni Afro-juju bakan naa ni duuru
tite Olushina a ma ran bi atoto arare. Eleyii to tun wa lekenka nibe ni awon
ijo Sir Shina Peters, eleyii to n mu arugbo ta kebekebe bi olomoge.
Awon ohun ara tuntun ti
Shina peter mu wo inu orin yii mu okiki kan eleyii to fi je wi pe totuntosi ni
onkorin naa fi gba ami eye bi igba eye le n kore wole.
Ko wa tan sibe, gbogo ile
Africa mitimiti ni akoko ti Sir Shina Peters tun ju awo orin re eleekeji sile,
eleyii ti won pe ni Shinamania. (Afro-juju series 2).
Ninu awo orin yii ni a ti
ri awon orin olokiki bi “Oluwa Yo Pese”, “Omo Bo” ati “Give Your Woman Chance”
eleyii ti won si gbo kaakiria agbaye titi di akoko yii.
E tun wa gbo, eniyan le pe
omi dudu laro, ohun to daju ni wi pe omi dudu ko le reso bi aro. Bi eniyan paro
wi pe amotekun ko yato sologini, iye eran ti won pa wale ni otito oro gidi.
Gbogbo aye ni won gba wi pe Sir Shina Peters ni oludasile Afro-Juju, lati ile
yii to fi de oke okun. Awon awo bi merindinlogun (16) ti Shina Peters gbe jade
lo si duro bi ere nla ti ko lre pare lailai, eleyii ti gbogbo re si dabi oosa
ajiki lawujo awon orin to gbamuse ile adulawo.
Lara awon orin ti Sir
Shina Peters gbe jade pelu egbe orin re to pe ni Sir Shina Peters and his international
stars ni .
Ace Afro-juju series 1 jade lodun 1989
Shinamania lo di irawo nla
lodun 1990
Dancing Time laye josi
lodun 1991
Nigba ti Experience si
dohun ti aye n dura lodun 1992
Awo orin Mr. President ni
baba Seyi gbe jade lodun 1993
My Child dori igba lodun 1994
Kilode, ni awo orin
ti Sir Shina gbe jade lodun 1995.
Ko wa tan sibe oo, lara
awon awo orin ti oko Sammie tun gbe jade ni
Love, eleyii to jade lodun
1996
Reunion lalewu lodun 1997
Playmate ni gbogbo aye ji
ri lodun 2000
Nigba ti Happy Hour foju
han lodun 2001
Pay back time jade lodun
2005
Splendour gbayii lodun 2006
D one for me ni awo orin
ti sir shina gbe jade lodun 2012.
Gege bi alaye sir shina
peter ninu orin re kan, o ni MC Hammer niluu Amerika, ise ijo ilu ati orin nise
ti won, won si fi se ohun rere. Shina Peter n ko? Bakan naa ni., Alakanbi nko?
Bakan naa ni. Kosi anini, ise orin lo so
Shina di olowo, olokiki ati eniyan iyi kiri agbaye bi goolu olowo iyebiye.
Aimoye omo ni Afro-Juju
creator bi, gbogbo won pata ni won ti soriire. Lara awon omo re ni ni Clarence
Peters, to je ogbontarigi, ilumooka ayawora nile Naijiria.
Bi
mo ba tile wa dake nibi mo ba de yii, ohun to daju ni wi pe Sir Shina Peter ko
ti dake orin kiko. Irawo to ju irawo lo si n tan, 777 is a number si n je lo nigboro, Ijo, ilu,
Orin, ede, asa re sin ta kaakiri agbaye.
0 comments:
Post a Comment