Smiley face

SÙÚRÙ GBÈ MÍ (apá Kẹrin) lati owo Oluko Ede Yoruba

Ẹ kú ojúmọ́, a sì kú u ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.
Èyí ni ìtẹ́síwájú ìtàn àládùn tí ẹ ti ń gbádùn. Ọba òkè ò ní pin gbogbo wa nípá o

—————————————————

Èsì ìdánwò mi jé òkan lára méta tí ó dára júlò ní ilé -èkó mi lódún náà. Ògá àgbà pe bàbá mi wón sì ro bàbá mi láti sa gbogbo ipá rè lórí kí n lè lo ilé èkó gíga.

Ògá àgbà fi kún n pé, wàhálà àsedànù bí eni se eyìn láì jinná ni òrò mi yóò jé bí mo bá kùnà láti tèsíwájú nínú èkó pèlú èsì ìdánwò tí ó késejárí tí mo ní yìí. Bàbá mi jéjèé láti sa gbogbo ipá tí ó tó láti rí i pé mo lo sí ilé èkó giga.


¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤¤


Ó johun pé bàbá mi so òrò nípa ìtèsíwájú èkó mi fún ìyá Adébáyò nítòrí pé bírí bí eni yí orógùn okà ni ìwa rè yípadà sí èyí tí ó wá burújàì, àsé késekése ni mò ń rí télè tí mò ń so pé mo rí nnkan, kàsàkàsà tí ó kojá àfenuròyìn ni mo wá ń rí báyìí.

Ìyá Adébáyò kìí lé ojà ní òpò mó, ó mòónmò lé ata kéré ju ti àwon ìyókù lo, ó sì kàn án nípá fún mi láti ta gbogbo rè tán láì ku òkan.

Púpò àwon oníbàárà mi ni wón fà séyìn àbí ta ní jé fowó òwón rajà òwón?
Nígbà tí ó yá, ó di wí pé kí n máa kiri nigbà tí ojà kò yá mó, béè sì ni ojà mi ò gbodò kù.

Orí ìrìnkiri ìtara ajé ni mo ti se alábàápàdé Olákúnlé. Omo olówó ni, àkérà ni àpèlé tí mo wòye pé ó dára jù fún un.

Àbèbí omo òdò won ni ó pè mí láti ra ata, léyìn ìdúnàádúrà Àbèbí lóun ò lè ra ojà mi pé ó wón, ni Olákúnlé tí ó ti ń wò wá láti òkè náà bá fenu sí i wí pé," Sé ìwo ò ri wí pé ojà arewà lò n ná ni? Bí olójà bá ti rewà, dandan ni kí ojà rè ó wón."

Olákúnlé bèèrè iye tí owó gbogbo ojà mi jé, mo sì so ó,ó ní kí Àbèbí ó da gbogbo ojà mi, ó sì sòkalè wá fún mi lówó. Léyìn tí ó sanwó tán, ó bèèrè orúko mi àti àwon nnkan mìíràn nípa mi.

Olákúnlé ní kí n má wulè máa pàráàro ara ká kí n máa gbé ata wá tààrà sí ilé àwon kí òun lè máa rí mi.

Báyìí ni mò ń fojoojúmó gbé ata fún Olákúnlé tí mo sì n jókòó síbè rojó di alé kí ara ó má baà fu ìyá Adébáyò. Ìyá Adébáyò gan ò bìkítà nípa ìrìn mi níwòn ìgbà tí owó rè ti ń pé.

Láàrin ojó méta, òrò ìfé ti wò láàrin èmi àti Olákúnlé, a sì ń bá eré àníyàn wa tèsíwájú fún bí osù mérin.

Àfèèmójú ojó kan ni ìyá Adébáyò pè mí,ó ní etí òun ti kún nípa òrò mi àti wí pé ara fu òun sí ibà tí ó ń se mí lénu lóóló yìí nítorí náà, òun yóò mu mi lo fún àyèwò ní ilé ìwòsàn.

Àyà mi là gààràgà bí mo ti gbó tí ó dárúko ilé ìwòsàn nítorí pé mo mò pé kìí se ìfé mi ló ní tó bè(Ní odún tó kojá tí àìsàn féè pa mí kú gan n kò fojú ba ilé ìwòsàn), ó ní láti jẹ́ pé òrò tí ó gbó nípa mi náà mu ú lómi gan ni.

IRÚ Ọ̀RỌ̀ WO NI Ẹ̀YIN RÒ PÉ ÌYÁ ADÉBÁYÒ GBÓ NÍPA MI? ǸJẸ́ Ó DÁRA BÍ BÀBÁ MI TI ṢE SÒRÒ NÍPA ÈKÓ MI FÚN ÌYÁ ADÉBÁYÓ? ìtàn yìí ń tèsíwájú.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment