Osán Já! Orún D'òpá!
Erín Wó! Àjànàkú Sùn Bí Òkè!
Ikú Pa Tèlèkú Ìdí Àrán, Ó Tún Dìgbà Kan!
Ikú Pabírí, Abírí Kú!
Ikú Pabìrì, Abìrí Rèwàlè Àsà!
Omo Fálétí Wá Lo Náà Nù-un Nì?!
Òsúnsún Bí Oré Ò Sí Mó! Awo Lo!
Ikú Pagílíntí, Onílù Bóòké!
Adébímpé Òjédòkun Wá Ti Lo!
Adébímpé Òjédòkun Erelú Omo
Èdìdàré Inú Ìgbé, Omo Ìyálágbòn!
Ikú Tó Pagbe- Ló Polówó Aró
Ikú Tó Pàlùkò -Ló Pelésè Osùn
Ikú Náà Ló Pa Lábónù L'Ájàsé
Ikú Ló Pa Lábólo Nígbóo Kútonu
Ikú Náà Ló PÒgírì Abòrìsà
Ikú Ló S'Oba Ejió Kánrin
Ikú Pewà, Ó Pòkín
Ikú Pakátá, Ikú Pagbe
Ikú Pòpò Àròyé-ikú Pa Wósòwósò!
Gbogbo Ebí, E Kú Ìrójú, E Kú Ará-féra-kù Babaà 'Re Tó Lo!
E Kú Àsèyìndè, E Kú Ìmókàn!
E Kúu Gbígba Kádàrá, E Kúu Gbígba Káshírá! E Kúu Gbígbà F'Ólóun; Olórí Ìsinmi Ni!
Àìgba Kádàrá Nìpìlè Àìbalè-àyà!
Ó Se! Ó Dìgbòóse!
Baba Adéwùmí Lo!
Baba Adédoyín Lo!
Baba Adéníyì Rèwàlè Àsà... Ó Di Gbéré!
Lati owo: Olanrewaju Adewusi
0 comments:
Post a Comment