Odidi osu mejidinlogun (18) ni mo lo ninu iya mi; iya mi ko tete ri mi bi.
Iya mi gbiyanju titi bi ki n wa saye, sugbon ko seese. Kosi ibi ti iya mi ko sare de.
Sugbon nigba to ya, iya mi pade babaalawo to gboju to lagbara pupo. O se alaye eni to wa nidi oro naa.
Leyin alaye, baba yii se ileri fun iya mi wi pe maa wa saye.
Lara ohun ti won fi seto aseje fun iya mi lojo naa ni anta ti awon kan tun mo si awonriwon.
Kete ti iya mi je eto aseje yii tan ni omo si bere si ni mu un. Bayii si ni mo se wa sile aye.
Ati igba naa ni iya mi ti n fi oruko anta pe mi. Bi mo tile ni oruko mi bi Babatunde, sugbon anta ni iya mi maa n pe mi. Oruko yii naa ni mo si je dagba. Omo ilu Osogbo ni mi nipinle Osun. - Antar Laniyan
0 comments:
Post a Comment