Smiley face

Onikoyi n pale ogun mo: Awon odo yawo ile igbimo asofin Abuja

Ni ojo Isegun, 25-07-2017, awon odo omo ile Naijiria yalu ile igbimo asofin to wa niluu Abuja lati fi ehonu won han nipa bi ofin se foju pawon re.

Ohun ti awon odo naa n pe fun ni sise ofin ti yoo fun awon odo ile yii ni anfaani lati di ipo isakoso mu ninu isejoba.

Awon egbe odo ti akomona won je #NotTooYoungToRun ni awon osise alaabo ko je kan wole sinu gbongan naa eleyii ti awon naa ko si salai di ile igbimo naa lowo ise won.


Won ni isejoba awaarawa to wa lode yii, anfaani gbodo wa fun awon odo lati di ipo agbara mu.

Siwaju sii, awon onwoye nipa oro oselu sakiyesi wi pe, ti iru ofin bee ba lo wa, awon omo oloselu naa ni yoo je mukundun anfaani naa ki i se awon omo mekunnu ti won ja fitafita bayii.

Sugbon sa, o dabi eni wi pe ero awon odo yii yato; ohun ti won wi ni wi pe, gbogbo odo ti won logbon lori ni won yoo ni anfaani lati dije fun ipo giga ninu oselu ilu Naijeria.


Gege bi itopinpin Olayemi Oniroyin, ni awon ibi kan, awon kan fidi re mule wi pe, ohun to jobi ehonu le pada di ogun ijangbara eleyii ti awon odo ile yii le gbe dide.

Aimoye odo ni won ko nise lowo, nigba ti awon agba ilu n yokun ti won si n je ogun awon omo won maye.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment