Smiley face

A se lotito loro Akanji

Lara ohun to ni ipa pataki to si semi lanfaani julo ni itoni ati ogbon ti mo ri ko lowo Akanji.

Akanji ki i se wooli, sugbon pupo ninu awon alaye ati oye re nipa igbe aye awon eniyan ti mo gbo lati enu re ti wa fojuhan.

Mi o le gbagbe, ni ojo kan, Akanji joko niwaju ile re. Okunrin kan an koja nita gbangba. Bi okunrin naa se foju kan Akanji, lo bo bata lese, o si n to Akanji bo wa. Bo se n sun mo Akanji lo n kuru lo n ga, bee ni i ki Akanji ni mesan-an mewaa.

Eniyan nla ni Akanji, emi gan-an mo. Akanji lowo lowo bee lo si mo awon eniyan nla lawujo.

Sugbon nigba ti okunrin naa lo tan, leyin to ya ki Akanji to si ba tie lo. Akanji so wi pe, awon eniyan a maa ka e kun tabi se aponle re koja bo ti ye nigba ti o ba wa ni ipo kan tabi oni agbara ti won le je anfaani re lojo iwaju tabi ti won je lowolowo.

O ni nigba mii, awon eniyan a maa se aponle re ti won ba se akiyesi wi pe o ni anfaani kan ti won le ponla lati owo re lojo iwaju tabi eyi ti won ri ponla lowolowo.

Sugbon kete ti won ba se akiyesi wi pe kosi agbara lowo re mo, tabi ko si anfaani kan ti won le wa si odo re mo, o ni ni akoko naa, bi o ba tile pe won ki, won ki yoo da e lohun.

A ye fe Akanji, sugbon emi o mo idi ti aye fi n fe e titi to fi salaye.

Bi o tile je wi pe aimoye nnkan to so nigba naa ni ko ye mi, sugbon awon laakaye jo bi asotele ati oro wooli lonii.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment