Lopolopo igba, ibi ti awon eniyan fojusi le ma je ona abayo. Lopo igba, awon eniyan a ma sebi ti eniyan ba ni ebun kan pataki to joju, paapaa julo awon ebun to ni i se pelu orin kiko, ise tiata, boolu gbigba ati bee bee lo, a maa je ki eniyan ni aluyo laye tabi se aseyori.
To ba si se wi pe okoowo sise ni, opo a maa ro wi pe bi oun ba se ri owo sise si bee ni ere oun yoo se po tabua. Sugbon ko ri bee nigba mi i.
Bi o tile je wi pe awon nnkan ti mo se alaye re loke yii se koko, sibesibe ki i se awon nnkan ti a le pe ni eroja to peye lati fi se odiwon aseyori ni yii.
Lara ohun kan to se pataki ninu igbega eda wa ninu ajosepo, eniyan ti a n ba sise tabi da owo po. Aimoye nnkan mi lo tun wa ti n se apejuwe abaje igbese eda, sugbon yoo wu mi lati duro lori ajosepo - Association.
Okoowo tabi ise eniyan le maa lo siwaju nipa ajosepo enikan ti eniyan ba sise tabi ti eniyan fegbe ti. Eniyan le ma fura lopo igba, nitori awon eniyan ti a n ba se yii le ma ko ipa kan to joju ti a le ri tokasi. Sugbon to je wi pe ibasepo won ran wa lowo lati goke. Bakan naa lo ri fun idakeji.
Pupo ninu olorin bi meji si meta ti n won korin papo, sugbon nigba to ya ti won tuka, okan ninu won ni i pada moke nigba ti awon to ku yoo si deni igbagbe.
Koda, lopo igba, awon ti a ko rokan si ni won pada tesiwaju nigba ti awon to ku tabi enikeji yoo si sun lo gbadari.
Adura mi ni wi pe ki iru e ma sele si P-square.
N ma tesiwaju lori koko yii laipe
0 comments:
Post a Comment