Smiley face

Orisi ewe meji to le yi ipo yin pada si rere

Kosi ohun kan ti a fe se atunse re ninu igbesi aye wa ti a ko le dogbon si. Bi ko tile bo soju ȩ tan, yoo yato si bo ti wa tȩlȩ to je ipo ibanujȩ.

Orisi ewe meji pere le ma wa: Ipinnu ati Agbara

Ohun kan pataki ti a ni lati se ni ipinnu, eleekeji ni agbara lati mu ipinnu naa se.

Lopa igba, agbara yii le je imo kan pato tabi asiri ona abayo ti ohun ti a n fe yoo fi te wa lowo.

Kosi ipo ti a ko le yipada. E fi oro lo awon to le ran yin lowo. E ri daju wi pe e ko simi titi ti ohun te n fe yoo fi teyin lowo.

Kosi ohun kan to wu yin ti ko le teyin lowo, ohun to se pataki ni ipinnu ati agbara.

Ki n to dake, kini ohun kan ti ko teyin lorun nipa igbe aye yin?   

Iru igbe aye wo lo wu yin? Kini ohun ti e fe gan-an?

Nje e ti pinnu lati yi ipo naa pada. Nibayii, eni lati wa agbara lati mu ero ati ala yin wa  simuse.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment