Smiley face

Bayii ni Adebayo Salami se bere

Bi o tile je wi pe omo ipinle Kwara ni sugbon ilu Eko ni won bi si lojo kesan an osu karun un odun 1953. Ilu Eko yiii naa lo ti kawe alakobere ati girama.

Lodun 1964 ni Oga Bello bere ise tiata nigba to darapo mo egbe osere kan ti nje Young Concert Party eleyii ti Ojo Ladipo je adari fun. Egbe yii naa ni won yii oruko re pada si Awada Kerikeri Theatre Group.

Ni odun 1978, Ojo Ladipo ti opolopo mo si Baba Mero koja lo sorun. Ni akoko naa, Oga Bello ti ni oye ise tiata gidi gan an,  eleyii lo mu awon omo egbe naa gba fun lati je adari won. Bi Adebayo se bere ni yii to si fi bee di irawo nla.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment