Smiley face

Oganla@50: Àwo orin to sọ Paso di ìràwò tí àwọn amòyé ń wá kiri ni yìí

Ní nǹkan bi ẹgbẹ̀rún ọdún sì àkókò táa wà yìí, yóò jẹ́ ohun àbùkù láti ṣe àlàyẹ́ nípa orin Fuji láì dárúkọ Wasiu Alabi Ajibola ọmọ Odetola fún akitiyan àti àṣeyọrí rẹ̀ nídìí oríṣi iṣẹ́ orin ti ọ̀pọ̀ gbà wí pé Sikiru Ayinde ló ṣe ìdásílẹ̀ rẹ.

Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kọkànlá ọdún 1967 ni wọ́n bí i ní agbègbè Mushin to wa ni ilu Eko Ọba Rilwan Akiolu.

Láàárín 1973 sí 1979, Alabi lọ sí ilé ẹ̀kọ́  Muslim Mission Primary School. Oganla tèsíwájú sì ilé ẹ̀kọ́ Nigerian Model High School láàárín ọdún 1979 sí 1984.

Kété tí Wasiu parí ilé ìwé girama ló ti yà sídìí orin kíkọ.

Àwo rẹ̀ àkọ́kọ́ jáde lọ́dún 1993 eléyìí tó pé ní Recognition. Ni ọdún 1994 ni Choices jáde.

Ọdún 1995 ni Orobokibo mìgboro tìtì. Àìmọye àmì-ẹ̀ye ni àwo yìí gbà, àwo yìí kan náà lo si fi Jibola hàn gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run eléyìí tí àwọn amòye ń wá kiri dòní. Àìmọye àwo ni Pasuma tí ṣe, àṣeyọrí rẹ nídìí ìṣe orin Fuji sì dabi àpáta Olúmọ eléyìí tí kò ṣe é fojú parẹ́.

Òní (27-11-17) ni ọjọ́ìbí Iba Wasila, ṣùgbọ́n kí n tó mẹ́nu kí i, mo bẹ̀ yín kí ẹ fún mi laye lati yàbàrà díẹ̀.

Stephen King ọmọ ilẹ̀ America lọ sọ̀rọ̀ kan eléyìí tó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ làákàyè. "Ohun tí wọ́n pé ní ẹ̀bùn tàbí talenti gbọ̀pọ̀ bí ẹ̀ko méjì kọ́bọ̀ kan. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ akíkanjú jẹ́ ohun kan pàtàkì tó mú àwon alaseyori gòkè àgbà."

Paso tí gòkè àgbà, mo sì gbà á láàdúrà wí pé kò ní jábọ́. Igba ọdún, ọdún kan ni. Àṣe

#HappyBirthdayỌ̀gáńlá

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment