Ogun layé, oníkálukú lọ ń rú tiẹ̀ kiri. Edumare níkan lo si le bẹ́ẹ̀dá tán ìṣòro rẹ́.
Ni nǹkan bí osù mélòó kan sẹ́yìn, ni pasito kan nílùú Eko, Pasito Olagorioye Faleyimu, ríran sì Funke Akindele wí pé àti lọ́mo láyé rẹ yóò nira ayafi tó bá kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà.
Àìmọye àwọn olólùfẹ́ Akindele ni wọn bẹ̀rẹ̀ si se àdúrà fún un wi pe àsọtẹ́lẹ̀ ibi kò ní sele sii.
Ìdùnnú ńlá lọ sí jẹ fún gbogbo ènìyàn nígbà tí wón bẹ̀rẹ̀ si ni rí ikùn Jenifa tí ń ga sókè. A tile gbọ́ wí pé oyún ìbejì ló gbé sínú.
Nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń retí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ Sulia, Stella Dimoko Korkus, oniroyin ayelujara ọmọ Naijiria to fi ìlú Jámánì ṣe ibùjókòó gbé iroyin míì jáde. Àlàyé rẹ̀ ni yìí:
"Insiders say Actress Funke Akindele Bello has been quiet because she is grieving the loss of the pregnancy we all thanked God for sometime back...........This is so sad!!!"
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Stella, inú ìbànújẹ́ ni Funke Aya Bello wá báyìí nítorí wí pé ó ti pàdánù oyún ìbejì rẹ̀.
Àdúrà wa si ni wi pe ki Èdùmàrè bá wà tú nínú, ko fi ọmọ rere míì rọ́pò fún un. Àmì
0 comments:
Post a Comment