Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama ni mo ní anfaani lati mo ìyàtò tó wà láàárín "Manslaughter" àti "Murder" eléyìí tí méjèèjì je oríṣi ẹ̀sùn tó ní í ṣe pelu ìpànìyàn nile ẹjọ́.
Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ ṣe ṣàlàyé lọ́dún náà, ó ní bí méjèèjì tilè mú èmi dání, ṣùgbọ́n ojú tí òfin fi wọ méjèèjì yato.
Murder ni i se pẹ̀lú ki ènìyàn mọ̀ọ́mọ̀ ṣekú pa ẹ̀dá ẹgbẹ́ rẹ nígbà tí èkejì, Manslaughter je ìpànìyàn nípa àṣìṣe.
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, tí ọdẹ, bá gbé ìbọn kọ́rùn láti pẹran nínú igbó. Níbi tó ti ń lọ nínú igbó, kí ìbọn ọwọ́ wá ṣèèṣì yín tó sì pa ara èrò tí ń bọ̀ leyin.
A ko le so wi pe, òde náà mọ̀ọ́mọ̀, fún ìdí èyí, ẹ̀sùn Manslaughter ni wón yóò dá fún un eléyìí tí ìjìyà rẹ yóò kéré pupo bí ó tilè jẹ́ wí pé ó la èmí lọ.
Eleyii to tun farapẹ́ẹ ní Attempted Murder". Eleyii je ìgbìyànjú láti ṣekú pa ènìyàn ṣùgbọ́n tí àbá náà kò jọ.
Bi o tile je wi pe ẹ̀sùn attempted murder kìí la ẹ̀mí lọ ṣùgbọ́n ìjìyà rẹ a maa ju ti Manslaughter lọ lábẹ́ òfin.
Ohun tó bí àlàyé yìí ni ìròyìn ọmọbìnrin amofin, Yewande Oyediran, to seku pa oko re, Lowo, lodun 2016 nílùú Ìbàdàn eléyìí tí wọ́n ti pada dajo rẹ lọ́jọ́ Aje to koja yii.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ní inú wọn kò dùn pẹ̀lú bí ìjìyà obìnrin náà ṣe jẹ́ ẹ̀wọ̀n ọdún méje péré.
Awon kan lo ye ki ìjìyà náà ju bẹ́ẹ lọ. Bí ó tilè jé wí pé àwọn ẹbí ọkọ fẹ̀sùn ìpànìyàn kan án ṣùgbọ́n ẹjọ́ Manslaughter ni wón padà dá fún un eléyìí tó ní í ṣe pelu ìpànìyàn nípa àṣìṣe.
Òfin fọ́jú, lọ́pọ́ ìgbà, ẹ̀ṣẹ̀ tí ọ̀daràn ṣẹ̀ kò ṣe pàtàkì bí kò ṣe bí wọn ṣe rojọ́ ni kọ́ọ̀tú. Ejo ti won ba ro àti eri tí wọ́n bá fi hàn ladájọ́ yóò dájọ́ lè lórí. Eleyii si ni onidajo Muntar Abimbola, to jókòó nile ẹjọ́ to gaju lọ nílùú Ìbàdàn ṣe.
A ni lati fi ìgbàgbọ́ sínú ẹ̀ka eto ìdájọ́ wá, kí i se gbogbo ìgbà náà là má naka àbùkù sì í nítorí ọjọ́ ọ̀la ilẹ̀ Nàìjíríà.
Èrò tèmi ni yìí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, inú mi yóò dùn láti rí èsì ohun tí eyin ro.
È seun
0 comments:
Post a Comment