Smiley face

Ọjọ́ tí Taju mẹkálíìkì ọrẹ mi dé láti Libya

Àìmọye àwọn ènìyàn dudu ni wọn ti ko àgbákò báyìí ni ni orile-ede Libya látàrí imunisin tàbí ìmúnilẹ́rú tí ń lọ lọ́wọ́ nibẹ́.

Awon aworan to jáde wa láti ìlú náà bani lọ́kàn jẹ́ púpọ̀. Wọ́n ón dana sun awon ènìyàn láàyè, wọn so ẹlòmíràn mọ́lẹ̀ bí ẹran, wọn na wọn, gun wọn lọ́bẹ sakasaka títí ẹ̀mí fi jáde lára won..

Mo ti wo fídíò náà bí ẹ̀mẹta, fún ìgbà meteeta, mi ò lè wo parí torí pé ọkàn mi kò gbé e.

Púpò àwọn ènìyàn ti wọn ko àgbákò yìí ló jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n làkàkà láti lọ sí ilú Òyìnbó nípa irinajo orí ilé àti omi ṣùgbọ́n tí ìrìnàjò wọn forisanpon.

Nígbà tí ilú òyìnbó kò ṣe é lọ, ilu Libya ni gbogbo wọn fàbọ̀ sì gẹ́gẹ́ bí ìlú tí eto oro ajé rẹ gbé sókè díè ní apá arewà ilé Áfíríkà.

Oro Libya to gba iroyin kankan yìí jé kí n rántí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ sí mi ní nǹkan bí ọdún 2000 sì 2001 nípa ọrẹ mi kan, Tajú mekaliiki, tó wo ilu Libya.

Libya sì dun gan-an nígbà náà, àìmọye ọmọ Nàìjíríà ni wọn lọ sibe. Ti won ba wale odun, bi igba ènìyàn dé láti ìlú Amerika tàbí London ni i ri. Won a maa se yatayoto bí Davido, omo bàbá olówó.

Àlàyé mi sí ń tèsíwájú...E ku oju lona

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment