Ìtẹ̀síwájú àlàyé mi ni yìí nípa ọ̀rẹ́ mi, Tajú Mẹkálíìkì. Eléyìí ni i ṣe apá kejì ìtẹ̀síwájú ìtàn mi. E máa bá mi ká lọ.
Ní àkókò tí mo ń sọ yìí. Tá a ba béèrè wí pé Lágbájá nkọ, wọ́n a ni ó ti lọ Libya. Bi a béèrè wí pé Tàmẹ̀dùn nkọ, wọ́n a ni oun naa wa ní Libya.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n gbọ́ iroyin ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní Libya ni won fòmọ́ ọkọ̀ tí gbogbo wọn kori sì Libya.
Bi a kò tilẹ̀ de Libya, a rí àwọn tó dé láti bẹ. A rí bí wọn ṣe ń jaye bí Ọba Lamidi tí wọ́n bá dé. Joojumo ni won wo aṣọ tuntun bí Ooni Ojaja.
Ilu Ìbàdàn ni won bi mi sì, ibe náà ni mo sì dàgbà sì. Ni agbègbè Mokola tí a ń gbé nígbà náà sì ni isele yii ti sele. Omo ẹ̀kọ̀ṣẹ́ mẹkálíìkì ni Taju, ṣùgbọ́n ó ti mọṣẹ́ dáadáa ní àkókò yìí.
Ní ọjọ́ isimi, inú garaji wọn láti ń gba bọ́ọ̀lú nítorí wọn kìí ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sande.
Àìmọye ìgbà ni Taju a ni kí fún òun lọ́wọ́ jẹun. Ki là jẹ́ ọ̀rẹ́ fún bí a kò bá lè ràn ara wa lọ́wọ́? Ohun tí mo bá ní ma fún Taju. Ọmọ ilẹ̀ ìwé lèmi, ọ̀dọ̀ àwọn òbí mí ní mo sì ń gbé. Mi ò mọ ohunkóhun nípa àwọn òbí Taju. Wokisọọbu wọn náà láti ń pàdé eléyìí tí kò jina sile ti wa.
Lọ́pọ̀ Ìgbà ni mo máa ń lọ bá Taju sere tí mi ò bá ní nkankan láti ṣe nile, àwọn oga rẹ kìí lé mi, torí wọn mo mi, wọ́n sì mọ àwọn òbí mi.
Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan, mo ń rékọjá lọ, mi ò rí Taju, mo sì yà láti béèrè rẹ. Ṣáájú àkókò náà, mo fura wí pé mi o ki n ri bi tí tẹ́lẹ́ tí mo bá ń kó ja lọ. Nítorí bí mo jáde nile tàbí mo ń darí padà sílé, iwájú wokisọọbu wọn ní mo ń gba kọjá. Nibo ni Taju lọ, kilode ti mi o se ri ọ̀rẹ́ mi mọ?
Alaye mi sì ń tèsíwájú...
0 comments:
Post a Comment