Ẹ tún káàbọ̀!
Eléyìí ni atejade kẹta nípa ìrírí mi nípa Taju mẹkálíìkì ọrẹ mi to de lati ilu Libya.
Mo fẹ́ tọrọ gáfárà láti fi asiko yii ki Ayọ̀ Ibrahim omo Balogun ti gbogbo ènìyàn mọ sì WizKid fún àmì-ẹ̀yẹ eléyìí tí ẹnikẹ́ni kò gbà rí ní ilé Adúláwò. Inú mi dùn, mo sì bá a yọ gidi gan-an.
O ya, ẹ jẹ ká padà sórí ọ̀rọ̀ Taju Mẹkálíìkì. Won padà fi yémi wí pé Taju náà tí wọ̀lú Libya. Lai rí, inú mi dùn mo sì bá a yo gidi gan-an.
Ninu ọkàn mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí ni finú ro wí pé kò bá dára tí Taju bá lè ráàyè tèsíwájú nínú ìṣe mẹkálíìkì rẹ nílùú Libya. Lai bá débẹ̀, mo ń rò wí pé Taju tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ mẹkálíìkì rẹ, o ti rí tajé ṣe, ó sì ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó padà wálé.
Bi inú mi ṣe dùn tó lọ jẹ́ kí n má ro báyìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ iṣẹ́ to n ṣe bákan náà ni mi o mọ ipò tó wà.
Léyìn tí Taju tí wá ni Libya fún bí ọdún kan àbọ̀ tàbí ọdún méjì, Tajú padà wale fọ́dún.
Taju jọmiloju gidi gan-an lẹ́yìn to de si Nàìjíríà. Ìjọlójú to se lo si pada di ohun tí mi ò lè gbàgbé lailai.
Kini Taju ṣe tí mi ò lè gbàgbé?
E pada wa si oju òpó yìí láti wá ká làbárè to ku.
Ẹ ku ìkàlẹ̀!
0 comments:
Post a Comment