Ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí ni yóò pé oṣù kan tí Kemi Olunloyo ọmọ gómìnà ipinle Ọ̀yọ́ nígbà kan rí, tí padà sẹ́wọ̀n fún ìgbà kejì lórí ẹ̀sùn kan náà.
Ti ẹ ko ba gbàgbé, nínú oṣù kẹta ọdún yìí ni awọn olopaa wa gbe Kemi nílùú Ìbàdàn tí wọ́n si gbé lọ siluu Pọtà.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn oniroyin ayelujara naa ni ibaniloruko jẹ.
Olootu HNNAfrica là gbo wí pé, o gbe e jade ninu ìròyìn rẹ wí pé, Pasito David Ibiyeomie to kalẹ siluu Pọtà a maa ba àwon ọmọ ìjọ rẹ sun.
Won da Kemi sile nínú oṣù kefa ọdún yìí ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kẹwàá oṣù kọkànlá ọdún yìí là gbo wi pe won tun kò aṣọ ẹ̀wọ̀n wá padà rẹ ní kóòtù níbi wọ́n ti n gbejọ rẹ.
Titi di àkókò yìí, akọsẹmọsẹ oniroyin to tun kawe gboye ninu ìmọ̀ nípa bí wọn ṣe n po ògùn òyìnbó, sì ń fi aṣọ penpe ọba jura ni Pọtà.
Bákan náà, ní àwọn àkókò kan sẹ́yìn, Kemi pé bàbá rẹ̀, Oloye Victor Omololu Olunloyo, ni ológun ìkà nínú iṣẹ́ iroyin rẹ.
Lara awon to tun naka àbùkù sì náà ni Pasito E A Adeboye ti ìjọ ìràpadà. Ṣùgbọ́n baba yìí kò ṣebí ẹni gbọ.
Kemi kò sai tún kọ́ ninu iroyin rẹ wí pé, Jide Kosoko n fi àwọn ìyàwó se ogún awure leyin ti osere naa pàdánù iyawo eleeketa tí ń ṣe Henrietta Kosoko.
Jide Kosoko kò ṣe ohunkóhun fún un ju wí pé, òun fa Kemi sì kootu Ọlọ́run lọ.
Ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀yí, Pasito David Ibiyeomie kò fà Kemi sì kootu Ọlọ́run, kóòtù ayé lọ gbe lọ ní Pọtà nibi wọn ti ni ko mu ẹ̀rí to fi idi iroyin rẹ múlẹ̀ hàn. Ṣùgbọ́n Kemi kò rí ohunkóhun mú jáde gẹ́gẹ́ bi eri wí pé lóòótọ́ ni Pasito ń bá àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ sùn.
0 comments:
Post a Comment