MoẸyin ènìyàn mi, máa bẹ yín láti fi òye gidi gbé àlàyé mi. Nítorí yóò tako ohun tẹ̀ẹ́ mọ tàbí ìgbàgbọ́ yin.
Ti ọmọ iya méjì bá wo yèwù, tí wọn jọ sọ̀rọ̀, tí wọn rojú koko jáde. A jẹ́ wí pé wọ́n n ba ara wọn so òtítọ́ ọ̀rọ̀ gidi ni.
E ma je n tan yín, à sìsọ gbaa ni wi pe ìwé ni i mú ní débi gida tàbí sọ ènìyàn di pàtàkì láwùjọ. Ìró ni.
Lara awon àṣìṣe tó dé bá wa ni yìí ti oríṣiríṣi àjálù fi ń wọlé si Nàìjíríà lára.
Ti ènìyàn kò bá mọ ìwúlò bàtà, ènìyàn le fi tolé gẹ́gẹ́ bí ohun èṣọ́ ilé .
Bákan náà pàtàkì ẹ̀kọ́ ileewe kìí ṣe lati le fi wáṣẹ́ tàbí ṣiṣẹ́ lẹ́yìn ẹ̀kọ́ kíkọ́.
Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn agbaniṣíṣẹ́ a maa fẹ́ni to ba ti kàwé gboyè.
Pataki ẹ̀kọ́ iléèwé nígbà tí wón sẹ̀dá rẹ ni Athens àti Rome ni láti jẹ ki ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan péye láti ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe lai wá ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. A tún lè pé ní ironilagbara láti pé lódindi gẹgẹ bí ẹ̀dá ènìyàn.
Gege bi àkọsílẹ̀, àwọn oǹwòye ìgbà náà bí Aristotle, Socrates, wòye pé, ó se pàtàkì fún àwọn ènìyàn láti ni ironilagbara láti lè yanjú àwọn ìṣòro tó bá ń jẹ jáde láwùjọ. Eleyii lo fa tí wọ́n fi seda ẹ̀kọ́ iléèwé kika.
Lónìí, àìmọye ìṣòro la n kojú bí àìríṣẹ́ ṣe àwọn ọ̀dọ́, ọrọ̀ ajé to pokurúmusu, aisi ààbò, iwa jẹgúdújerá àti bẹẹ bẹẹ lọ.
Ojúṣe àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n lọ sí iléèwé ni lati jẹ àtúnṣe si àwọn ìṣòro àwùjọ, ṣùgbọ́n o jo ni loju wí pé ìṣòro ni òpó wọn tún jé fún àwùjọ nípa dìdarapo mọ òkè aimoye awon ọ̀dọ́ ti n wáṣẹ́ láwùjọ.
Ta wá ni ká dá lébi? Àwùjọ, ìjọba, òbí, àwọn ọ̀dọ́ àti gbogbo wa pata là jẹ̀bi.
Ati sọ kókó pàtàkì tí ẹ̀kọ́ da le lori nu. A bẹ̀rẹ̀ sí rí gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀gùn ọlá, igbega tàbí láti jẹẹ̀yán pàtàkì lawujo.
Ìdí ni yìí tí ọ̀pọ̀ fi ń kówó ra sabuké. Nígbà tí eto eko wá sí di bẹẹ di yẹyẹ.
Ijoba gan-an ko mú eto ẹ̀kọ́ ni pàtàkì bí àwọn ìlú òkèèrè.
Ń má tèsíwájú...
0 comments:
Post a Comment