Kí n má parọ́ àsìkò kò ti to fún Nàìjíríà láti bọ lọ́wọ́ àwọn olóṣèlú amúnisìn. Bi o tilẹ̀ jẹ́ wí pé òye àwọn ènìyàn tí ń lá ju ti ateyinwa lọ, sibẹsibẹ a kò ti débẹ̀.
1.Ilànà eto iyansipo àti idije fún ipò faye gba jẹgúdújerá. Lati gba fọ́ọ̀mù idije lábé ẹgbẹ́ òṣèlú fún ipò ààrẹ, ó kéré ju, milionu mewaa owó ni ẹni náà yóò san eléyìí tí kò dájú wí pé yóò padà soju ẹgbẹ́ naa.
A kò ti sọ ìpolongo eléyìí to je ise gan-angan. Enikan tilẹ̀ sọ wí pé ti ènìyàn yóò bá díje fún ààrẹ, iyen àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣe tán , eni naa gbọ́dọ̀ ṣètò ọgbọ́n bilionu pamọ́ .
2.Lopo igba àwọn ará ilú sebi àwon ni awon yan adari. Ìró ni. Awon Bọrọkini alenulọrọ ni won yan fun wa. Mi ò so nipa èrú ṣíṣe nipa eto ìdìbò. Ohun ti mo n sọ ni yii, ki awon ara ilu to dibo fún Obasanjo ni 1999, awon kan ni won jókòó tí wọ́n sì sọ wí pé Obasanjo la fẹ. Bakan naa ni won se nipa Olú Falae. Èyí yòówù tí a lè dibo fun nínú àwọn méjèèjì, kí ṣe ìfẹ́ ọkàn wa, ero àwọn kan ni.Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ seri ni ijoba ìpínlẹ̀ ati ìbílè.
3. Ètò ọrọ̀ ajé wá to dórí kodò je ko nira láti yan olórí gidi. Ebi ń pa awon ènìyàn, eniyan ti ebi ń pa tí wọ́n fun lẹ́gbẹ́run márùn-ún kò wá dibo, se ko ni di? Bẹ́ẹ̀ ni ilu òkèèrè, àwọn ará ìlú ni won dawo fún ẹni wọn ba fẹ láti díje.
4. Ènìyàn rere kò le dije ipò kò wọlé ní Nàìjíríà lai ma ni àtílẹ́yìn àwọn jẹgúdújerá, ọ̀jẹ̀lú, ìkà, àti ọ̀dájú olóṣèlú. Sẹ ẹ ranti wi pe Fela, Gani Fawehinmi tí dije rí? Bákan náà ni ilakaka MKO padà ja sofo náà ni.
Ìró laye n fe, òtítọ́ ni wi pe olùgbàlà wá kò sì nítòsí.
0 comments:
Post a Comment