Pupo àwọn ọmọ Nàìjíríà si ni ìgbàgbọ́ nínú Buhari. Ṣùgbọ́n títí di àkókò wo ni awon ènìyàn yóò lè mú ara ró fún Buhari?
Atiku Abubakar tí darapo mo ẹgbẹ́ PDP báyìí, ó si dájú wí pé ìlàkàkà rẹ ni lati ja ìjọba gba lọ́dún 2019.
Bi o tile je wi pe Buhari kò ti kede wi pe oun yoo tèsíwájú lẹ́yìn ijoba àkọ́kọ́ yìí, ṣùgbọ́n gbogbo wa loye wí pé, kò sí eni ti wọn yóò gbe sílé owó tí yóò wu kò jáde kíákíá.
Ti àlàyé mi bá jọ bí ìró, ọjọ́ tí ẹ bá rí Robert Mugabe kẹ́ ẹ béèrè.
Bi Buhari kò tilẹ̀ fe se, awon ti wọn jẹ lábẹ́ ìjọba rẹ̀ kò ní gbà. Nítorí bí kò bá ti sórí lọ́rùn , gbogbo ara a sì dokú.
Jù gbogbo rè lọ , Buhari ni lati sapá rẹ kì 2019 tó wọlé de. Nítorí púpò àwọn ìlérí tó ṣe tí kò ti i muse tí di ohun tí Atiku n lọ láti takòó báyìí.
1 Airisẹ àwọn ọ̀dọ́ sì ń burú sii.
2 Eto ọrọ̀ ajé wá kò dùn rárá.
3 Iná mọ̀nàmọ́ná sì ń ṣe mọ́namàna
4 Àwọn wọn ọ̀jẹ̀lú tí ráyè sáwo ìṣèjọba Buhari
5 Eto ọ̀gbìn kò gbèrú
6 Ìjọba n gbìyànjú nípa ètò ààbò ṣùgbọ́n Boko Haram kò ti kásẹ̀ nile.
7. Ìyípadà rere kò ti bá ètò ẹ̀kọ́, ìlera, ẹ̀ka onidajo abbl.
Gégé bí ohun tí mo sọ , ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn sì ni ìgbàgbọ́ nínú u Buhari. A o kan lè sọ ìgbà tí wọ́n yóò mu ara dúró fún un kí wo to yari.
Ṣùgbọ́n kò to di wi pe àkókò náà yóò dé, Buhari ni lati yege púpọ̀ nínú àwọn ìlérí rẹ kì eto ìdìbò 2019 tó wọlé dé .
0 comments:
Post a Comment