Díẹ̀ nínu àlàyé ẹni tó kán sí Seun Egbegbe ni yii.
"Igba àkókò kò ní yìí tí ń má ṣe àbẹ̀wò si Seun. Oju to ti moni ri kò gbọ́dọ̀ so wi pe oun ó moni mọ.
Kosi ìgbà tí mo bá yoju si ti èmi kì bá ra oúnjẹ nile oúnjẹ ìgbàlódé dani. Maa tún fún lowo díè pelu.
Ṣùgbọ́n ó ti ṣe díè seyin tí mo ti rí gbeyin nítorí mo rìn ìrìnàjò seyin odi.
Ni akoko poposinsin odun ti n bo yii, aimoye awon ènìyàn ni won se abewo si ọgbà ẹ̀wọ̀n láti fi ife han si awon to wa nibe. Emi na si ro wi pe ko burú tí mo bá tún kan sì Seun, awa meta la lọ sibe.
Seun tí dudu, ènìyàn pupa tí di dudu pátápátá. Seun o lómi lara tele, ko tun wa ri oúnjẹ gidi je. Ti ènìyàn bá rí, ẹ ro wi pe o ni kọ́kọ́rọ́ HIV ni
O dupe lowo wá nibi to ti n dupe lómi tí jáde lójú rẹ. Ó sì wí pé, oun ti gba ìpín òun tó bá jẹ́ ipin òun ni yii.
Orisirisi nǹkan ni àwọn ènìyàn ń sọ kiri nípa Seun Egbegbe ṣùgbọ́n ohùn tó wà leyin Ọ̀fà jÒjé lọ. "
Kilo wá leyin Ọ̀fà to jÒjé lọ?
E yẹ àtẹ yìí wo fún abala karun-un ìròyìn yìí
0 comments:
Post a Comment