Smiley face

Ọmọbìnrin ọdún mejo, wọn fi ipá ba sùn kí wọ́n to sọ òkú rẹ sórí akitan

Rògbòdìyàn tí bẹ silẹ báyìí ni orileede Pakistan eléyìí tó ti mú ènìyàn méjì ló.

Rògbòdìyàn eléyìí tó bẹ̀rẹ̀ bi ifẹhonu hàn nípa bí àwọn aṣebi kan ṣe fi tipátipá bá Zainab, ẹni ọdún mejo sún tí wọn sì tún ṣekú paa.

Àìmọye ènìyàn ní wón tu jáde ní Kasur, tí wọn sì ń pe fún idajọ òdodo.

Ìtara àwọn ènìyàn pelu bí ijoba ati awon agbofinro ṣe fi owó yẹpẹrẹ mú oro naa lọ mú àwọn ará ìlú kọlu wọn eléyìí to mu àwọn olopaa tabon mo ènìyàn méjì.

Zainab tí wọn tí ń wá  ní nǹkan bí òjò mélòó kan sẹ́yìn ni wọn ba òkú rẹ lórí akitan. Ìwádìí sì fi hàn wí pé, wọn ba ọmọ náà sún tipátipá ni pelu bí gbogbo ìdí rẹ ṣe faya pẹrẹpẹrẹ.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment