Smiley face

HBD JayHemKay: Olajumoke Ewatomi gbàrà dá!

Sebi ọdọọdún làá rorogbo. Ọdọọdún báyìí náà là romo òbí lórí àte. Òní ojo kọkànlá oṣù kìíní ọdún táa wá yìí ni Olajumoke Ewatomi ọmọ Ajadi tí àwọn kan tun mo sì Morufa Bodija le lodun.

Arábìnrin yìí kan náà ni oludasile idije oge sise tí a mo sì Miss Ojuloge Beauty Peagent, eléyìí tí olubori idije náà ni anfaani lati rin ìrìn-àjò lọ síluu òkèèrè.

Ṣáájú kí òjò ibi rẹ tó wọlé, ní ọmọbìnrin yìí tí ń dúpẹ́ lowo Olúwa nípa àwọn ipenija tí ó borí. Gbajugbaja sorosoro orí afẹ́fẹ́ náà kò sai tún dúpẹ́ lowo awon ẹni bí ẹni tí wọn ṣe atileyin fún ún ní àwọn àkókò yìí.

Àwa náà darapo mo ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ènìyàn káàkiri àgbáyé láti bá Olajumoke yọ lónìí fún ayẹyẹ ojo ibi rẹ tó wọlé de.

Ìgbà ọdún, ọdún kan ni. Àṣẹ

H A P P Y  B I R T H D A Y!
#Ogbontarigi osere tiata
#Obabirin Sorosoro
#Agbaọjẹ onise oge
#Ojulowo Amuludun

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment