OLAJUMOKE PART 3 :
Báyìí ni awon mejeeji dagbere o digba fun ara wọn.
Sugbon ni ale ọjọ yìí Jumoke kole sun rara nitori ori ironu ló wà titi ile fi mọ ati pe sise alabapade Oriola jẹ́ oun iyanu loju rẹ.
Lori ironu yìí lowa leyin ọ̀sẹ̀ mẹta. Ni osan ọjọ́ kan láàrín ọjà ló tún ṣe alabapade Oriola.
Inu re dun o si salaye bi ironu se gba gbogbo okan re fun Oriola. Oriola ni bee gege lo se emi naa ati pe emi naa kole sun daradara mo lati ọjọ ti a ti pinya, ati pe mo ti sọ̀rọ̀ rẹ fun awon obi mi won si ti pe ki n fi o se aya.
Bééni Jumoke naa ni awon obi mi naa ti fowo si nigbati mo soro re fún wọn. Báyìí ni Jumoke se mu Oriola lo s'ile lati lo fi han awon obi rẹ.
Lẹ́yìn eyi ojo ń gorí ojo osu ń gorí osu bẹẹni ife won ndagba síi. Ṣùgbọ́n Oriola nikan lo n wa Jumoke wa sile won, leyin odun kan awon mejeeji pinnu lati se ìgbéyàwó.
Won dajo igbeyawo s'ona, awon mejeeji si ń múra sile fun igbeyawo alarinrin.
Oriola ń palẹmọ bẹẹni Olajumoke naa n palẹmọ won ti ra oríṣiríṣi aṣọ ati onírúurú bata olówó iyebiye.....
Alo ń tesiwaju ...
Orísun: Emmanuel Oluwafemi Felix
0 comments:
Post a Comment