OLAJUMOKE PT 4 :
Wọn dajọ ìgbéyàwó sọ̀nà, ọjọ́ pé won file ponti won f'ona road.
Ariya n ṣan, oúnjẹ lo jantirere, gbogbo ara ilu lojeun ajerele won tun mu àmùrè lè.
Gbogbo ènìyàn lo n fi ìgbéyàwó Olajumoke tọrọ. Àwọn ore re gan-an ń gbàdúrà pe k'Olorun fun won l'oko bii Olajumoke.
Gbogbo awon ore Oriola towa nibe lojo na iwin ni gbogbo won sugbon won gbe awo ènìyàn wọ ni.
Gbogbo ara ilu lo ń kí Olajumoke ku ori ire nitori kò tii si iru ìgbéyàwó alarinrin bẹẹ ri ninu ilu wọn.
Nígbà tí akoko to lati maa mu iyawo tuntun lo, nkan iyanu kan sele láàrin àwọn iwin.
Won pe arawon jo won si n sọ ede ti awon ara ilu awon Jumoke ko gbo.
Nígbà tí won pari ipade won, Oriola mu iyawo re lowo won ń jọ lọ niwaju...
Ẹ maa ba wa bo..
Orísun: Emmanuel Olufemi Felix
0 comments:
Post a Comment