Smiley face

Lẹta mi sí Yakubu Fanami tí Boko Haram ṣekú pa

Yakubu, mi ò mọ bóyá wà ni anfaani lati ká leta mi yii. Ṣùgbọ́n mo fi dá ọ lójú wí pé,  má gun orí òkè méje, máa sì kó orúkọ rẹ sì ọna méje níbi tí gbogbo ayé yóò ti rí. Mo sì fi dá ọ lójú wí pé, ìtàn Nàìjíríà ko ni fojú pa ọ rẹ fún ìwà akin, ọmọniyan àti ìfẹ́ orile-ede rẹ.

Lọjọ Jimoh to kọjá, àwọn ikọ Boko Haram kò ado olóró sábẹ́ ọmọ obìnrin kékeré kan eléyìí to dá iborun bora. Ise ikú tí wọn rán ni wí pé, kò lọ ṣekú pa àìmọye àwọn ènìyàn tí wọn fẹ kirun jọsin sì ọba Allah.

Yakubu kofiri ọmọ tí wọn rán nise ikú náà. Kosi àkókò fún àlàyé, Yakubu wọ jáde láàárín ọpọ ènìyàn, ibẹ ni ado olóró náà ti bú. Yakubu àti ẹni wọn rán nise ikú náà nìkan ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Iléèwé girama olodun kẹrin (SS1) ni Kaleri to wá nIpinle Borno ni Yakubu wa. Yakubu sebi akoni, ó fi èmi rẹ lélẹ̀ fún àìmọye tí kò bá kú iku aimọdi.

Yakubu máa sì mi títí di ojo igbende.

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment