Nínú èrò mi, mi ò ro wí pé ìṣòro Nàìjíríà yóò dópin nípa gbígba àwọn ọ̀dọ́ láàyè nínú isejọba nìkan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìdùnnú mi ni lati ri àwọn ọdọ tí wọn di ipò ìṣàkóso mú.
Ṣùgbọ́n pàtàkì ibẹ ni ètò, ìlànà tàbí àgbékalẹ̀ wá eléyìí to fàyè sílẹ̀ fún àìṣòdodo, jegudujẹra, olè àti àwọn ìwà ìdọ̀tí orísìírísìí láwùjọ wá eléyìí tó ti mú ifasẹyin de bá orile-ede Nàìjíríà lapapọ.
Àwọn inú tó ti gòkè ni ètò ati àgbékalẹ̀ eléyìí tí kò fàyè gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìṣòro tí a ń koju lónìí.
Ẹ jẹ ka tí ibi ìsáná kíyè sóògùn. Tí àwọn ọmọ Naija bá lọ sókè òkun, púpò nínú àwọn ìwà pàlàpálá tó kún ọwọ́ wọn nílé ni wón kii le danwo tí wọn bá dé ìlú òyìnbó nítorí ètò ati àgbékalẹ̀ tí wọn ni.
2019 kò ní pẹ de, àfojúsùn wá kò yẹ kó jẹ ìpè fún ìjọba tó fún àwọn ọ̀dọ́ láyé nìkan bíkòṣe eléyìí tí yóò mú àtúntò bá ètò ìsèjọba, ìlànà àti àgbékalẹ̀ ìṣèlú tàbí ètò ìlú tó se gbára lé. Eléyìí tí yóò jẹ kò nira fún àwọn ènìyàn láti ṣe ohun tí kò yẹ. Ẹ kú àsìkò yìí.
Olayemi Olatilewa
Twitter/IG @OlayemiOniroyin
yemoford@gmail.com
0 comments:
Post a Comment