Akíkanjú olopaa ọlọtẹlẹmuyẹ to mú ògbólógbòó ọ̀daràn tí ń jẹ Evans nijosi, Abba Kyari tí mú ọkùnrin kan tí ń jẹ Adeola Williams, ẹni tí inagije rẹ ń jẹ Ade Lawyer.
Ọkùnrin agbanipa tí ń jẹ Ade Lawyer yii lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ gege bí ọ̀daràn to ṣekú pa Ganiyu Ayinla ẹni tí inagije rẹ ń jẹ Pinero.
Pinero to jẹ amugbalẹgbẹ (P. A) fún siamaanu egbe NURTW tí idumata, Azeez Lawal, tí inagije rẹ ń jẹ Kunle Poly ni wọn ṣekú pa lọjọ ketalelogun oṣù kinni odun 2018 (23-01-18).
Gege bí alaye Ade Lawyer, òní Kunle Poly gan-an gan ni wọn rán òun sì láti pa ṣùgbọ́n Pinero ni ibon bá lọjọ náà.
Nínú àlàyé rẹ lo tí so wí pé alaga ẹgbẹ́ NURTW tí ipinle Eko nígbà kan ri, Alaaji Akanni Rafiu tí ínagije rẹ ń jẹ Ọlọhunwá lọ rán òun niṣẹ naa.
Iroyin sì ń tesiwaju... Ẹ yẹ abala keji (pt2) ìròyìn yìí wo nibi : www.olayemioniroyinblog.com
Àwọn ènìyàn to wá nínú foto: Ade Lawyer àti Akanni Olohunwa
Fún ipolowo àti ikede ẹ lè kan sì wa pelu nomba yii 08032394964 yemoford@gmail.com
Twitter &IG: @OlayemiOniroyin
0 comments:
Post a Comment