Nígbà tí Ade Lawyer ri wí pé òpin tí de, gbogbo ohun tó pamọ pátá lo ṣàlàyé fun àwọn oniroyin. Alaye ògbólógbòó agbanipa náà ní yìí:
"Kìí se ìgbà àkọ́kọ́ ní yìí tí Olohunwa yóò má rán mi nise ipaniyan. Awon ènìyàn bí mẹ́rin ni mo ti pa fún un rí sẹ́yìn."
Kódà, kẹ le mọ wí pé òtítọ́ ni ọrọ mi Nígbà ìjà òun rẹ àti MC Oluomo Oshodi, ènìyàn méjì ni mo mú balẹ fún Olorunwa. Agbanipa nise mi. Awon ọba pàápàá a má gbesẹ fún mi láti payan."
Ade Lawyer kò dárúkọ ọba kánkán ní pàtó nígbà tó tún ṣe àlàyé rẹ síwájú sii
Ọlọ́run wá pé mi lórí ago, òní òun nise pàtàkì fún mi. Igba ti èmi rẹ pàdé. Ó ni àwọn owó kan wà tó yẹ kó má jáde sí òun lọ́wọ́ gege bí alaga onimoto àná. Ó ní ṣùgbọ́n Kunle Poly lọ ń ṣe adina fún àwọn owó náà.
Ó ní òun sì ni ẹni tó mu Kunle Poly wọnú egbe onimoto. Òun gbé lẹhin tán, ó tún wá ń fi ehin náà bù òun je.
1.5m ni àdéhùn ẹmi àti Ọlọhunwa . Ó ju ẹsẹ mbẹ náà lọ sí ti ko 500k fún mi. O ni ti ń bá sise tán, òun yóò san balansi tó kú. Ṣùgbọ́n ikú ko mú Kunle Poly, Pinero lọta ibon mi bá lọjọ náà tí mo lọ sise náà.
Iroyin sì ń tesiwaju... Ẹ yẹ abala kẹta (pt3) ìròyìn yìí wo nibi : www.olayemioniroyinblog.com
Àwọn ènìyàn to wá nínú foto: Ade Lawyer àti Akanni Olohunwa
Fún ipolowo àti ikede ẹ lè kan sì wa pelu nomba yii 08032394964 yemoford@gmail.com
Twitter &IG: @OlayemiOniroyin
0 comments:
Post a Comment