Adé Lawyer, ẹni tó sọ wí pé Alaaji Akanni Olohunwa lo rán òun láti ṣekú pa Kunle Poly kò ti dake àlàyé rẹ.
"Kunle Poly là fẹ́ pa, Pinero niku mú lọ ohun tó ṣẹlẹ̀ tí ṣẹlẹ̀ kò sì ṣíṣe ju ká gba f'Ọlọ́run lọ. Gbogbo ìgbà ti mo ba ti pe Ọlọ́runwá wí pé kò wá fún mi ni balansi mi lọ má ń so fún mi wí pé òun kò ti fẹ́ bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ báyìí.
Igba to yà ni ó gbé ọkọ Camry kan fi rán àbúrò rẹ̀ sí mi. Ṣùgbọ́n mo sọ fún wí pé mí kò fẹ́, mo ní Jeep ni mo fẹ́ eléyìí to padà gbé ranse. "
Ọkọ Jeep náà wá lọdọ àwon Ọlọpaa báyìí. Gbogbo àlàyé Ade Lawyer ni Alaaji Ọlọhunwa so wí lè kó rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Ò ní oun kò bẹ Ade Lawyer nisẹ láti pa ẹnikẹ́ni.
"Ò títọ ni mo fún ní 500k, ìdí tí mo fi fún ní wí pé, ó ń hale mọ mi wí pé òun yóò ṣe ẹbi mi ijamba. Mo mọ̀ wí pé òní wàhálà ènìyàn ni, mi ò sì fẹ́ wàhálà fún ebi mi.
Nípa moto, àbúrò mi lo gbé moto mi fi tọre fún un eléyìí tí mi ó tilè mọ nípa rẹ rárá," Olorunwa náà so tẹnu rẹ
Ṣùgbọ́n sá, ìwádìí àwọn olopaa sì ń tesiwaju láti mọ wulẹ̀ wulẹ̀ oro naa.
Àwọn ènìyàn to wá nínú foto: Ade Lawyer àti Akanni Olohunwa
Fún ipolowo àti ikede ẹ lè kan sì wa pelu nomba yii 08032394964 yemoford@gmail.com
Twitter &IG: @OlayemiOniroyin
0 comments:
Post a Comment