Smiley face

ÌGBÈYÌN láti owó RASBAM (1)

Àròko lásán ni ìtàn yìí, kò ní ohunkóhun se pèlú enikéni.
              
                             -1-
Àdìsá àti aya rè wà ní ìdí èkùró gégé bí ìse won, sé àgbè paraku kúkú ni Àdìsá omo Báòkú.

Kìí se àgbè olókó nlá béè sì ni a kò lè pè é ní àgbè alároje nítorí pé owó tó n rí tùjo ló fi tó Omoniósanjó tí i se igi àkósé rè títí dé ilé èkó gíga fásitì ti ìlú nlá, owó yìí kan náà ló sì fi tó Àjoké tó jé àbígbèyìn rè jáde ìwé kewàá.

“Kí elédùá jé kí omo yìí tà ni o, kó mówó gidi bò ni ìkiri.” Àdùnní ló rawó èbè sí olódùmarè.

Sé látìgbà ti Sanjó ti wo fásitì ni gbogbo nnkan ti le koko bíi ojú eja fún won. Ekukáká ni wón fi n jeun èèkan soso lójúmo, kò sí owo kankan tí Àdìsá fi le dá oko mo.

Ònà kan soso tó kù tí tórókóbò n gbà wolé fún won náà ni isé epo fífò tí Àdùnní yàn láàyò.

Ìdí nìyí tó fí jé pé tokotaya ló n dìjo pa èkùró léyìnkùlé ilé Báòkú tí Àdìsá jogún.

“Kí Àjoké tà ni o, torí kò sí ònà ta tún le gbà rí owo fi ránnsé sí Omoníósanjo” Àdìsá sòrò tàánútàánú.

Aya rè dá a lóhùn, ó ni “Mo jérìí elédùá, kò jé dójú tì wá, àti pé gan baálé mi kín ni Àjoké fé je bó bá kiri dé?”

“Kín làwa náà ri je? Sebí gaàrí ni àwa náà wà mu.” Ni èsì tí Àdìsá fún aya re.

“Haà! Ní omo olómo tó ti kiri òòrùn lo látàárò”

“Sèbí òun náà kúkú rí gbogbo rè, à n sèse erin à n jèje èlírí nítorí Omoníósanjó, bí Omoníósanjó bá ti parí èkó rè àbùsé bùse, ìgbádùn dé.” Àdìsá ló wí báyìí pèlú ìrètí.

“Béè ni o, bí Sanjó bá ti setán ní fáfitì ìyà wa dópin nù-un.”

“E kúulé o, mòómi” bí Àdùnní se gbó ohùn omo rè tó kiri epo pupa lo látàárò ló ti fò fèrè dìde tó n kì í ní mésàn án méwàá kí Àjoké tó jáde wá sí èyìnkùlé.

“Bóo ni? Oko mi Àjoké, omo ajílálàá òsó; omo ajífojó gbogbo dára bíi egbin…”

Àjoké kò jé kíyàá rè kì í délè tó fi jáde séyìnkúlé pèlú igbá epo lórí tó ní “mòómi, e ti le kììyàn jù o jàre”

“Bóo ni? Só o tà?” ni ìbéèrè tí ìyá àti bàbá rè panupò bi í
“A dúpé, ajé bugbá je, òní ni ojà Àgbagbà ní abà Afára, n lèmi àt’Àsàbí bá kúkú fèèkan gbója wa lo síbè lo tà, e wò ó, àfi bí i pé àwon ará a abà Afárá ò lépo lábà won ni ”

ó so igbá epo orí rè kalè “gbogbo ojà pátá ni mo tà tán, kódà mo tún fowó lé e pèlú” Àjoké sàlàyé, inú àwon òbí rè dùn dédìí, tèríntòyàyà ni Àdùnní fi téwó gba owó ojà lówó omo rè. Wón fí ìdùnnú won hàn, wón sì se òpòlopò àdúrà fún un.

Àdìsá jé kó yé omo rè pé bísé ò bá péni, enìkan kìí pésé, ó so fún un pé bó bá ti di àfèmojú òla ni kó tètè  te okò létí lo sí ìlú nlá láti lo kó owó nàá fún ègbón rè.

Àjoké bèèrè oúnje rè, ìyá rè sì so fún pé gaàrí làwon náà mu. Àjoke fi tayòtayò bu gaàri s’ómi, ó sì mu ú pèlú ayo okàn.

Léyìn tí Àjoké mu gaàrí tán, ó so fún won pé òun fé dé òdo òré òun Àsàbí láti lo gba owó àjo òun kí òun lè kó o kún owó tí n kó lo fún Sanjó ní òla. Inú won dùn púpò láti gbó ohun tí Àjoké so, wón dúpé lówó Olórun tí kò se àwon omo won méjéèjì ní omo ìyá awùsá. Àjoké dágbéré, ó sì korí sí ilé àwon Àsàbí.
      *        *          *           *              *

Adéròmólá Agbábíàká n rin abúlé Alákùko kiri, ó jo ó lójú bí gbogbo agbègbè se le wà ní ìdákéróró, kó sí ariwo orin níwájú béè kò sí ariwo okò tàbí ariwo àwon oníjàgídíjàgan léyìn bí i ti ìlú Ajé tó ti wá.

Ó dé abé igi ìgbá kan, ó dúró, ó gbé ojú sókè ó wo igi náà yíká. Gbogbo agbègbè náà pa lóló àfi dídún àwon eye oko àti ìró esè rè tó n da ewé gbígbe ilèélè láàmú.

Pèlú bí àyíká yìí se rí, ó dá Ròmólá lójú gbangba gbàngbà pé bí akékòó tó n múra ìdánwò bá wá síbè láti kàwé, kò ní kùnà ìdánwò náà.

“Báwo ninú mi ò bá se dùn to tí mómì bá le gbà kí n ma wá se weekend níbí bàí.”

Ròmólà ló n so nínú ara rè báyìí sùgbón òun gan alára mò lókàn rè pé àlá tí kò lè se ni, ìyá rè ò le gbà láéláé, níse ló pe ìyá rè lórí ago bó se dé ibi isé ní ojó Etì tó paró fún un pé ibi-isé rán òun ni isé pàtàkì kan ní ìlù Òyó, ó sì di ìròlé ojó Àìkú kí òun tó dé.

Bó se kúrò ni ibi isé ló lo gbé okò rè sí ilé tirè tó n gbé tó sì korí sí ibùdókò níbi tó ti te okò létí wá sí Alákúko láti wá wo baba baba re.

Ròmólá réèrín músé nígbà tó rántí iró nlá tó gbé kalè fún ìyá rè, ó wò yíká ó rìn lo rìn bò, èèkannáà ni Ròmólá pariwo tòòò “yeeeeeeeeeeeeeh” ó sáré fi owó méjéèjì di esè òtún rè mú, láìpé esè rè kú rìrì ó sì subú lulè.

        *          *            *                *            *        *

Bí Àjoké se dé òdò Àsàbi, ó bá a lénu iná dídá wón sì jo pawópò dá iná oúnje náà, Àjoké náà sì fi àmàlà gbígbóná àti obè gbègìrì pèlú eran ìgbé sínú kí o tó rántí ohun tó torí rè wá bá Àsàbí nílé.

Àsàbí kó owó àjo òré rè fún un, ó sì sìn ín sónà díè kí wón tó dágbére fúnra won.

Bí Àjoké se n to ònà tóóró tó lo sónà agboolé Agbábìàká lo ló gbó tí enìkan sàdédé logun tòòò, èrù kókó ba Àjoké ó dúró gbári lójú kan, léyìn bí ìséjú kan Àjoké ki eré mólè ó n sá lo.

Ó n sà padà ló sí ònà ibi tó ti n bò láìpé ó dúró, ó ní "E dúró ná, bí wón bá tiè wá bi mí pé kín ló n lé mi, kín ló n lé mi gan?

Àjoké n bi ara rè léèrè, ó sì pinnu láti lo yojú wo ohun tó n selè gan.

Àjoké se okàn akin, ó yó kélékélé lo sí ònà ibi tó tí gbó ariwo, o yojú wo ona inú igbó náà lókéèrè, o rí okùnrin kan tó di esè mú tó n kérora. Àjoké sáré sí i.

"Bòdá, kín ló mu yin?" Àjoké bèèrè lówó Ròmólá, Ròmólá ò le fèsì ó nawó sí esè rè.

Àjoké bèrè wo esè rè.

"Háà, ejò" Àjoké pariwo, o sáré wo àyíká ó ri okùn ó so mó òkè ibi tí ejò náà ti sán Ròmólá.

Àsé bí Ròmòlá sé dúró sí abé igi náà, iwájú ejò oká ló dúró sí tí ò fura, tí òun àti ejò náà sì jó n se fàájì lábé igi.

Àsìkò tí ejò múra láti máa bá tiè lo ni Ròmólá náà gbìyànjú láti rìn káàkiri abé igi. Esè òtún tí Ròmólá gbé sókè tó dá padà sílè báyìí, orí ìrù oká ló gbé e lé lórí.

Inú bí afàyàfà ó fìbínú sòrò sínú, ó ní "e wo ìkà omo adáríhunhun yìí ke, jéjé mi ni mò n gbatégùn Elédùmarè sára kó tó kó òsì orí rè dé, kí n sì tún fibí silè fún kó tó rán mi lórun àrèmabò, ó tún fé so mí di aláàbò ara, ko tó ba tèmi jé n ó ba tìe mó'rin" afàyàfà fi ìbínú yán orí, ó sán Ròmólá je, ó pòsé ó wí sínú pé "oníranù" ó sì bá tirè lo.

Àjoké já ewé kan léyìn tó so okùn mó Ròmólá lésè tán, ó ra á mó owó ó fi sí ojú ogbé ejò náà.

"E pèlé, e tiraka dìde ka mo lo" Àjoké fà á dìde, Ròmólâ tè yénkéyénké, ó fi ara ro Àjoké wón mórí lé òná agboolé Agbábíàká.

Agbábíàká nà sí orí àga àgbàntara níwájú ilé rè, ó mú òpá tó fí n sìkejì ara lówó, ó n fi òpá owó rè na ilè bí ìgbà tí omodé bá n fi igi seré béè ló n korin pèlu ohùn gbígbòn pé:

“Àwa n jayé lóko bí àwon ìjòyè ni,
Àwa n jayé lóko bí àwon ìjòyè ni,
Orí òkéré, orí àparo tere lórí iyán tìnrín lófun..” ó húkó léraléra kó tó dáké lo gbári, léyìn ìséjú díè ó gbé orin rè padà.

“Àwa n jayé lóko bí àwon àwon àwon…” ó tajú kán ó rí tí omobìnrin kan n fa Ròmòlá n bò lóòókán.

Ó tiraka dìde ó fi òpá rè tilè ó sáré lankulanku lo pàdé won.

“Dérò, kín ló dé? Emi ló mú o?” Agbábíàkà bèèrè pèlú ìpayà.
“Grandpa, e relax, ejò ló kàn…”

Agbábíàká gé òrò mó o lénu ó ní “Ejò se kín ní? Haà! Déròmólá o ò sì sàánú mi”

“E wòó bàbá, wón nílò ìtójú tó péye, bí kìí bá se Olóhun tó fi mí se gaàrí tírà won ni bóyá àkùko ò…”

Agbábíàká gé òrò mó Àjoké lénu ó ní “pádà, èèwò, àkùko kákùko kìí yóò ko léyin enikéni nínú yín, wòó,"

Agbábíàká kojú sí Àjoké "o seun, modé yìí ìwo náà ò ní kàgbákò"
"Àmin bàbá" Àjoké dáhùn.

Agbábíàká sún mó Ròmólá ó fà á lówó.

"Sùgbón, modé yìí, ó kù nìbon ró, jé á jo síra mú u d'ódò Ewégbèmí"

"Grandpa, ìyen ò need mó, mo ti wà okay tó bá di àárò òla mà lo tójú ara mi nílé" Ròmólá fi Agbábíàká lókàn balè.

"Wà óókeyì àbí kín ló so ná? sé oró kan-in-kan-in ló pe oró ejò ni? Bóyá ló mò pé oró ejò tó n wò un ó ju oró ìbon lo"

"Béè ni o, bòdá e jé kí wón tójú yín, oró ejò ò gbodò pé lára rárá o" Àjoké kín Agbábíàká léyìn.

Ròmólá gbà sí wón lénu, gbogbo won sì korí sí ònà ilé Ewégbèmi. Àjoké di Ròmólá mú lápá òtún, Agbábíàká gbá owó àlàáfíà rè mú.

Bí wón tí n wo ilé Ewégbèmí lóòkan, ojú Ròmólá bèrè sí í sú, esè rè wúwo kò se é gbé mó, ó dúró, gbogbo àyíká dúdú lójú rè.

Jìnnìjìnnì bo Àjoké àti Agbábíàká, Agbábíàká bèrè sí ní gbòn, àágùn sì bòó.

Àjoké wòye ohun tó n selè, ó wó Ròmólá tó ti lo lórí ìdúró, àánú abiamo se é, ó tiraka bó síwájú Ròmólá, ó bèrè èyìn bí i ìyá tó fé gbé omo pon, ó fi agídí wó Ròmólá sí èyìn rè, ó n tiraka sáré ló sí ònà ilé Ewégbèmi, Agbábíàká n sáré lankulanku tèlé won...

ÌGBÈYÌN n tèsíwájú...

© RASBAM 2018

Orísun: Rosheedat Bamidele Amusat

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment