Smiley face

ÌGBÈYÌN láti owó RASBAM (2)


                           -2-

Àjoké n tiraka sáré ló sí ònà ilé Ewégbèmi pèlú Ròmólá léyìn rè, Agbábíàká n sáré lankulanku tèlé won, bí wón se súnmó ilé Ewégbèmí ni Ewétólá jáde síta tó rí won, Ewétólá sáré sí won, sé Ewétólá sì taagun dáadáa ní tirè, kíá ló gba Ròmólá léyìn Àjoké tó sí pòn ón sí èyin rè bi omo, Ewétólá pon Ròmólá wolé lo, Agbábíàká sì sáré tèle e.

Àjoké jókòó lé orí pèpéle ó n mí helehele bí eni sèsè sá eré márátóònù tán.

Àjoké jókòó tí ara rè fi balè díè, ìgbà tó di èyin bíi ogún ìséjú tí kò gbóje enìkan ló bá dìde nílè, ó gbon yèrì rè nù ó sì korí sí ònà ilé won.

Ewétólá gbé Ròmólá wo yàrá ìtóju lo, ó té e sí orí ení ó bèrè tìí o mú abe ó fi sá gbéré yípo ibi ojú ogbé náà léyìn èyí ló wá bèrè ofò pípè sí esè náà, Agbábíàká n fí inú se àdúrà orísirísi gbogbo bí Ewétólá sé n saájo Ròmólá. Láìpé oró ejò náà bèrè sí ní jáde lésè Ròmólá.

"Háà! Elédàá mi mo dúpé o" Agbábíàká dúpé ó fi owó gbâ elédàá rè mu.

Ewégbèmi wo yàrá wá.
"Haà! Agbábíàká Òré mi, ka sí nñkan?" Ewégbèmí bi òré rè léèrè.
"Mèwàá sí sonù o, omo re l'ejò sán je" Agbábíàká dáhun
"Ewétólá, bó wá ni?"

Ewégbèmí bí Ewétólá léèrè

"A ti dúpé baba mi" Ewétólá fèsì ó dìde dúró "ká dúpé lówó àwon irúnmolè tó bá wá dá èmí arákùnrin I pàdà, díè ló kù kó sodá sí sánmò keje, bí wón bá i pé díè si ni orin tá n ko i kó la ò bá mó on ko" Ewétólá sàlàyé.

"Haà, mo dúpé" Agbábíàká tún dúpé lówó elédàá rè léèkan sii.

Ewégbèmí sún mo Ròmólá, ó bèrè tìí ó gbé orí Ròmólá sókè, o ni;

"Epinrin bale o ro pinrin
Poroporo bale o ro poro
Ewe ogungun bale oro gbanikoko, gbanikoko
A difa fun baba oyeku oke-apa
Ti won npe ni oyeku san panna
Emi ni o yeku nu lori awo
Eji-oye
Ifa ni o yeku nu lori awo
Eji-oye, ifa ni o ye kunnu lori awo
Eji oye
Orunmila k’o o ye ku nu lori re
Adéròmólá, ìwó domo owó lónìí

Omo owó kan i kú lójú owo"
Agbábíàká n se àse bí Ewégbèmi sé n ki esè ifá. Ewégbèmí pe Ròmólá léèmeta, Ròmólá sín ó yajú ó wò yíká.

"Pèlè, ìwo ti domo ikú lónìí, ikú ò ní hun fi ó se, wòó Ewétólá bá n bu àgbo èrò wá fún un lágbàlá"

Ewétólá sáré lo sí àgbàlá ó bu àgbo wá fún Ròmólá, Agbábíàká gba àgbo ó gbé e sí Ròmólá lénu, Ròmólá ba enu jé kí o tó fi tipátipá mu ìwònba tó mu.

Kín ni Ròmólá mu àgbo tán si, àsùnfonfon n tèfon ló fi se.

Oorun tó sùn lo báyìí àlá orisirisi ló bèrè sí lá, ó lálá rí ara rè tó n bá ejò seré, ó lálàá títí ó lálá pé ejò gbé eérìndínlógójì mílíònù náírà f’óun,hmmmmmm àlá mà kúkú gò o.

Òwúrò ojó kejì ló tó tají, ó dìde jókòó, ó nà pònpòn, ó yán hòò, ó wò yíká ó rí Agbábíàká àti Ewégbèmi tí wón n fi elékúté sán èko.

“Pèlé, bóo ni? Àlàó ò kó, ará òjé ònpetu…” kò jé kí Agbábíàká kìí délè tó fi bèèrè pé: “Grandpa, lady yen n kó?”

“Ilédì? Ilédì? Èwo tún ni ti ilédì nínú òrò tó wà nílè yìí? Ewégbèmí o ò wa gbà mi, sé kìí se pé omo i tí n bá àwon ebora se?”Agbábíàkà kojú sí Ewégbèmí.

“Grandpa, ohun ti mò n bèèrè ni omobìnrin tó mú mi wá sílé” Ròmólá sàlàyé.

“Toò, omobìnrin lèyin alákòwé so di ilédì” Ewégbèmí sòrò pèlú èrín kèékèé

Agbábiàká sàlàyé fún Ròmólá pé òun ò dá omobìnrin náà mò nítorí pé àgbà ò jé kí òun ríran kedere mo àti pé jìnnìjìnnì tó wà lára òun kó jé kí òun lè fi èmi ìmoore hàn sí i débi pé òun ó bèèrè omo eni tí se.

Ó ká Ròmólá lára, ó sì pinnu pé bí ara òun bá ti se dáadáa títí ìròlé òun yóò rin gbogbo agbègbè náà yíká láti wá omobìnrin náà rí.

Ròmólá mu ògì gbígbóná tí Òòsàtólá, ìyàwó Ewégbèmí bá a pò. Wón sì padà sí ilé won.

Bí Ròmólá se jókòó ló rántí èro ìbánisòrò rè, ó sáré mú un jáde lápò.
“88 missed calls” ara rè kó tìò bó se rí iye ìpè tó wà lójú èro ìbánisòrò rè, bó se fé tè láti mo àwon tó pè é ni ìpé kan tún wolé, ó tè é ó gbé e sétí…

            *          *            *                *            *        *

Láti ìròlé ojó Etì ni Bólá tí n pe olólùfé rè tí kò gbé e, ó rò ó wí pé bóyá ó wà ní ìpàdé pàtàkì tó lo fún ni kò jé kó ráyè gbé ìpè òun.

Okàn rè balè pé ní kété tó bá ti rí ìpè òun ni yóò pe òun padà.

Nígbà tó di déédé agogo méwàá ààbò alé tí kò rí ìpè rè tó tún pè é padà tí kò gbé e ló tó mò ón lóràn.

Bólá pe ìyá olólùfé rè láti bèèrè bóyá wón gbúròó rè sùgbón Fadéké jé kó yé e pé òun náà tí pe omo òun ní àìmoye ìgbà tí kò gbé e, ó wá fi Bólá lókàn balè pé kò ní s’éwu tí ilè bá ti mó òun yóò pe ògá rè.

Òkan Bólá ò balè, ó bèrè sí ro onírúurú èròkerò “àbí ó ní accident ni? Àbi wón ti jí phone è ni? Àbí ó ti bó sí owó àwon eni ibi ni?”

“Olóhun ò ní jé” Bólá sòrò síta ó tàkà dànù lórí ìbùsùn rè láìpé oorun gbé e lo.

Kò pé púpò tí Bólá sùn lo tí ó lálàá rí olólùfé nínú igbó aginjù kan tí òun àti ejò ràbàtà kan jó n wòyá ìjá, ejò náà wé mó láti esè dé orùn, ó lanu láti gbé olólùfé rè mì ni Bólà sárè ta jí.

Ó sáré dìde jókòó, ó n mí helehele, ó mú èro ìbánisòrò rè ó rí i pé aago kan òru sèsè lù ni, ó tún pe èro ìbánisòrò rè, ìgbá mìíràn yóò dún, ìgbá mìíràn kò ní lo rárá. Báyìí ni Bólá se tí ilè fi mó.

Bólá kò wè, kò fonu tó fi korí sí òdò ìyá olólùfé rè. Bó se wo yàrá ìgbàlejò ló bá ìyá olólùfé rè tó n parapòrò káàkiri.

“Mummy, sé e ti rí i?” ni ìbéèrè tí Bólá fi kí Fadéké káàárò.

“Bólá mi ò rí o, mo tiè tún wá pe ògá è, ó jé kó yé mi pé àwon o rán an ni anywhere, pé àti twelve ló ti toro ààyè kúrò ní ofice lójó Friday” Fadéké sàlàyé fún Bólá

“Háà! Mummy, kín la wá ma se báìí?” Bólá bèèrè pèlú omijé lójú.

“F’okàn e balè dear, kò ní sí problem, jé kí n wolé mú key motor, nígbà tá bá dé odo Dérò, ó dá mi lójú pé ó ma mo bí àbúrò è se rìn?

“okay ma”

Bí Fadéké se gun òkè lo láti lo mú kókóró okò ní Bólá tún pé olólùfé rè wò kò dún jálè tí Ròmólá fi gbé e.

“Hello baby”

“Haà! Ròmólá, látàná”

“Má bínú baby, mo busy gan lánàá yen ni.”

“O busy pèlú àwon àsómú e àbí?

E wà pèlú won ní gbogbo àná le o se ráyè tiwa, mo ti mò pé o ò le pa ìwà…”
“baby kò rí béè, I was bitten by a snake.”

“SNAKE?”

Bólá pariwo “báwo ló se selè? Sé nínú hotel àbí báwo? Bólà bèèrè pèlú ìpayà.

“Ìlú wa ni mo wà, má worry, mo ti wà okay, jòó torí olóhun má jé kí mummy mo o, mà á má sàlàyé fún e tí mo bá dé lóla, love you.”

Ròmólá pa èro ìbánisòrò. Bólá gbé èro ìbánisòrò kúrò létí.

“Kín ló se snake? Ta ni snake se? Fadéké pariwo bèèrè bó sé n sòkalè bò.

“Ro… Ro… Ro…” Bólá n kálòlò Fadéké pakuru mó on.

“Sòrò kí n tó ya é je” ó jágbe mó Bólá.
“Ròmólá ni, ejò bù ú je”

“Yeeeeeh, mo gbé o, Ròmólá ti pa mi, níbo ló wà báìí?”

“Ìlú won”

“Ìlú wo? Yeeeh, àfìgbà tí Ròmólá kó bá mi po, ta ni mo fé pè báìí? Wòó Bólá, jé a lo” àwon méjéèjì se wìrìwìrì jáde.

          *          *            *                *            *        *

“Grandpa, tó bá ti se díè si, mo fé lo wo bóyà mo ma rí ilédì àná yen” ó sòrò pèlú àwàdà, ó réèrín lórí ìbùsùn Agbábíàká

“Toò, o ò jé ó di ojórò mó?” Agbábíàká bi í léèrè

“Kín ló n jé ojórò?” Ròmólá bèèrè

“Owó ìròlé tí òòrún ti wò, gbogbo nnkan lèyin alákòwé i mò”
“ e mò pé aago méjìlá ti fé lù, mi ò fé kó tó ìròlé kí ilè má ba à sú kí n tó padà”

“ó dáa, bo bá ti rí ilédi, ko ya mú dé ilé lódò mi ká lé kí i o”

“mo ti gbó.” Wón gbó ìró dídún okò. Fadéké sáré fi agídí pá iná okò níwájú ilé Agbábíàká, ó sílèkùn okò ó sáré sòkalè nínú okò, ó sáré sí enu ònà, ó fi ìpá sílèkùn tìbínútìbínú, ó sárè wolé, Bólá náà sòkale ó dúró sí ara okò.Fadéké sáré wo yàrá, enu yà wón láti rí i.

“Mó…” kí Ròmólá tó pè mómì jálé, ó ti sún mó Ròmólá, ó fi sòkòtò gbé e sókè bí ìgbà tí olópàá rá òdaràn mú, ó n wó o lo síta, Agbábíàká sáré mú igi rè, ó se lankulanku tèlé won. Fadéké fi agídí wó o déta.

"Mummy, e ní sùúrù" Ròmólá n pàrowà fún ìyá rè.

"Àbí o fé kí n sìwí fún e ni? Sébi tó dágbére fún mi rè é, ó yá" Ó n ti Ròmólá lo sídìí okò.

"Aya mi, se sùúrù, kò kúkú..."
"Bàbá e jòó, e má ba tèmi jé, e má pa wón fún mi be se pa bàbá won, e má k'óríburúkú ara yín ràn mi"

"Hàhà mu..." Fadéké gbé e lénu s'óhún, ó sílèkùn okò, ó ti Ròmólá wolé lágídí ó tìlèkùn okò, òun àti Bólá náà wolé sókò, okò sí, Agbábíàkà n wo okò lo, ó n mirí tomijé lójú.

Bí wón se wo ìlú Ajé tààrà ilé ìwòsàn ni Fadéké lo, dókítà se àyèwò fún Ròmólá, ó sì fi dá Fadéké lójú pé kò sí oró ejò nínú ara rè mó, wón bá a we ojú ogbé náà, wón sì fún un ní òògùn tí yóò ma lò.

Bí wón se délé ni Fadéké bèrè sí bú ramúramù bí i olóólà ijù.

"So ri pé òpònú afófungbému ni é, bí kìí bá se béè o ò ní paró fún mi ko wá gba òdo bàbá játijàti yen lo"

"Mummy" Ròmòlâ fi ìbínú dìde níbi tó jókòó sí ó ni "e è lè máa pe grandpa mi ní bàbá játijàti lójú mi, eni tó kù fún èmi àti bòdá mi ní bàbá nìyen nao"

"Ìwo lo mò, à n gba òròmadìe yín lówó ikú, e lá o jé ké e rákìtàn lo jè, bàbá yen á kàn pa yín dànù bó se pa bàbá yín lásán ni"

"Àsìkò ti daddy ló to, àtipé gan sebí..." Fadéké gé òrò mó on lénu.

"Wos wobí, mi ò ráyè ejó wéwé, mo ti pe ògá e, ó ti ni òun fún e lósè méjì láti fi sinmi, inú ilé i la jo ma wà, gbàgbé nípa pé òun lo sílé òdò e ni osù merin sígbà ta wà yí"

"Mummy, só le tóyen ni?" Ròmólá bèèrè

"O ò ní megabyte ko bi google léère" Fadéké fèsì, ó pòsé, ó kúrò níwájú won. Ròmólá jókòó Bólá sún mó on ó ní "wòó Ròmólá, mi ò ni paró fún e, òótó òrò ni mómì n so fún e, ìwònba ló ye kéèyàn sún mó àwon family..."

"BÓLÀ, jé kí eléìí jé ìgbà àkókó àti ìkeyìn to ma dá sí òrò tó ní se pèlú family mi, tán bá n sòrò family yín nílé yin ko lo ma dá sí i" ó pòsé ó dìde "Oníbàjé òsì, àntí olófòófó" ó mó Bólà lójú kó to wolé lo.

  *        *          *         *        *  
"Sé oríburúkú ò wá sí lára mi lóòótó? Àbí ta ni kí n ro tèmi fún?

Mo se bí bí 'ón se bí mi ón bí gbogbo omo, mo dàgbà mo deni obìnrin, mó gbéyàwó ayé gbó òrun pàápàá mo, ayé súre pé èyin ìyàwo mi ò ni m'ení, èyìn òdún márùn-ún laya mi tó finú soyún, njé kó tún fèyin gb'ómo pòn, a tún bèrè òwò àbíkú, ìkúnlè mésàn-án ni Kòsókô Àrèmú tó dúró, Kósòkó ó dúró lásán èmí ìyá rè ló fi rópò. O mà se o, ayé pe n láya mì'ïn mo kò jalè, mo re Kosòkó láti pínnínsín títí tó fi d'eni olá, omó sì n tójú mi, sèbi ojú gbogbo yín ló se lójó burúkú èsù gbomimu tí Aláwèdá bá n kó oúnje wá, sèbí Aláwèdá n pàdà sílé ló ko àgbákò ikú oró lójú pópó, ìkà níku se o, oró nlá gbáà níku tó rí mi nílè tó mú Aláwèdá mi lo dá mo.

Àwèdá omo ara òjé ònpetu, omo a pajá fún won ráwo,
Èlà mokò n ò gbodò jeye ègà,..."

Agbábíàká bú sékún, ó n hu bíi omodé, Ewégbèmi àti Àjàsá n pàrowà fún-un.

"Aya Kòsókò wá n lé àwon omoomo mi lára mi, ó mò se o, ìku o ò sé dáa o! E dákun, sémi n mo pa Kòsókó ni?' ó tún bú sékún.

Ewégbèmí fi owó lé e léjìká, wón túbò n pàrowà fún un.

Bí Àjoké sé dé ni ìròlé láti ìlú nlá tó ti lo kó owó fún Sanjó ni ó só fún ìyá rè pe òun n bò.

Ó mú orí lé ònà ilé Ewégbèmí láti lo wo Ròmólá. Ó dé ilé Ewégbèmí kò bá enikéni, ó pariwo títí kò rí eni dáa lóhùn, ló bá tún mórí lé òná ilé Agbábíàká.

Bí Àjoké se sún mó ilé Agbábíàká ló rí i tí àwon méji n pàrowà fún Agbábíàká

tó n wekún mu bí eni òfò sè, Àjoké káwó lórí o ní "Háà! Ìkúnlè abiamo o, àfìgbà tí bòdá yìí padà jé olóhun nípè". Ó mirí tàánútàánú, ó padá sílé pèlú ìbànújé àti ìrèwèsi okàn.

                  

ÌGBÈYÌN n tèsíwájú...

                               © RASBAM
                                  2018

Orísun: Rosheedat Bamidele Amusat

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment