- 3 -
Sé wón ni bá a bá dá ogún odun pípé ní pé; béè bí a dá ogbòn osù ó n bò wá ku òla, èyí ló dífá fún Omoníósanjó omo Àdìsá tó parí odún kerìn rè ní ilé èkó gíga fásitì ti ìlú Nlá.
Bí èèyàn g’esin nínú tokotaya won kò ní kosè, inú Àjoké pàápàá dùn dédìí, níse ni ayò kún’nu gbogbo wón lójó tí Sanjó gba ìwé èrí rè dé, sé ilé ìwé ìlú Nlá kò sí lára àwon ilé ìwe gíga ti n so òdún mérin dí odún márùn-ún, méfà, méje fún àwon akékòó won.
Bí akékòó kò bá ti ní ìsòro kankan nínú èsì ìdánwò rè, kò sí ewu lóko fún’rú u akékòó béè àfi gìrìgìrì àparò.
Oba òkè sì kúkú ké Sanjó, ó mo mìtìiti ìwé léyìí tó fún ní ànfààní láti wà lára àwon akékòó tó kékòó gboyè jàdé pèlú ipò onípele kìn ín ní tí àwon olóyìnbó n pè ní “first class”.
Bàbá àti ìyá rè wà dúpé lówó olórún fún oore tó se nínú igbésí ayé omo won, wón se òpòlopò àdúrà fún un.
Sanjó náà kò sàì dúpé lówó àwon òbí rè fún akitiyan won lórí òun láti inú oyún títí dé ibi t’óun dé lónìí.
Sanjó wà sèlérí regede bíi ilè bí ení fún àwon òbí rè, ó sèlérí láti tún ilé tí wón wà ko, ó sèlérí láti ra okò tó bágbàmu fún won, kò sàì sèlérí láti rán won ló sí ilé olúwa bí òun bá parí àgùnbánirò tí òun sì rí isé gidi.
“Háà! Elédàá mi mo dúpé, àsé èmi náà o jeun omo láyé mi.”
Àdìsá fi tayòtayò dúpé lówó olóhun oba tí ìyàwó rè sì mú orin sí enu:
“Emi la ò ní yò sí?
Emi la ò ní yò sí?
Bá a ti fé ó rí, béè náà ló rí
Emi la ò ní yò sí?”
Àdùnni bu ijó kèékèé, Àjoké pàápàá kò jé kí orin ìyá rè sòfò, òun náà gbé owó ijó genge.
“E lo fi okàn yín balè, àsìkò àtijeun omo yín ti dé, kò dè ní jó yín lénu lágbára olóhun” Sanjó mú u dá àwon òbí rè lójú gbogbo wón sì panupò se àmín sí àdúà àti ìlérí Sanjó.
“Bùròdá Sanjó, a kú oríire náà, e dákun e bá n fi òró ìwé tèmi náà sókàn o, k’émi náà wo fáfitì lódún tí n bò” Àjoké so èdun okàn rè síta sé ohun tí n dun ni ní pò lórò eni.
“Ìwo kó kántankàntan re s’óhùn-ún o jàre, ojà Àkèsán lo pe fáfitì ni? Àbi ‘ón se fáfitì f’óbìn-in? Àdìsá ló jágbe mó Àjoké báyìí.
“Bàámi kín ló dé? S’émi ò ni tèsíwájú mó ni?”
“Àjoké, òótó ni daddy so, obìnrin ni é nàó, ta ma fi owó ribiribi rán e níwèé tán, tóko e á so pé full housewife lòun fé kó o se, gbogbo owó ta bá wá fi rán e ní university…”
Àjoké kò jé kí ègbón rè sàlàyé délè tó fi pariwo “háà” pèlú ìbànújé àti ìjákulè.
“Àjoké, to be sincere, mò n sòrò pèlú ìrírí, o sa mo òrè mi Ayòadé ta jó wá sisé àgbàró ni time tí mo fi sèsè wo school, olówó ni daddy e bo se n wò ó yen, but àntí e tó jé àkóbí tí daddy won ran ní school ló kó bá àwon yòókù tí daddy won ò fi rán won ní school mó, aunty yen se masters tán ló bá lo fé ààfáà kan, nìyen bá há aunty, wón bá a rí isé, ó ní kò to sunnah kóbìnrin má a sisé…”
Àdùnni gé òrò mó on lénu, ó ni “Bí obìnrin ka mìtìiti ìwé téle, sébi ìdí ààrò náà ló mo.”
“Òrò asiwèrè ní yàtò, n ò lè náwó lórí ohun tí n o ní jèrè, obìnrin niwo, ànfààní wo nìwé fé se obìnrin?”
Àdìsà kín won léyìn.
“Kò tiè sí ohun tó burú nínú kóbìnrin kàwé sùgbón okùnrin tó bá wù kó fé obìnrin tó kàwé kó rán an fúnra rè”
Sanjó fèsì lé ohun tí bàbá re so.
“Sé eyin ti rán ìyàwó té e fé fé níwèé? Àbí séyin lé fé púrúntù be se kàwé yìí? Àjoke bi Sanjó léèrè tìbínútìbínú.
“Wòó, mó pàkúta sórò gidi tá n so jàre, kó o kó kátikàti re bó síta”
Àdìsá jágbe mó Àjoké.
“Bùòdá mi, l’éyin tí mo lérò pé e o bá bàámi sòrò” Àdìsá yo bàtà lésè ó fé lè é mó Àjoké, Àjoké gúnjìká, ó rójú kókó kúrò ní èyìnkùlé lódò won.
“O mò se o, eni a mò gbójú okùn lé ò j’eni a gba o, Bùòdá Sanjó! Bùòda Sanjó!! Bùòdá Sanjó!!! Sé pé èèyàn kàwé ò pé è kéèyan k’ogbón orí?
Àbí e è wa gbó òrò ìbànújé tí wón n so níròlé ni, òrò tí púrúntù ò gbodò mo so jáde ní n jáde lénu ègbón mi, háà! Ibi tí mo mò fojú sí ònà ò mò gbabè yo o, sé àgbèkèlé mi ò ti wá dòfo báyìí?
Háà! Sè àfojúsùn mi ò ti wá já sásán báyìí? Ìwo Olórun oba, lémi tí mo tí n ríra mi bí i omo fáfitì, tí mo ti n wora mi bíi alákòwé, ìgbékèlé ènìyàn asán mò ni o”
Àjoké n ronú lórí ení àjàkù tó sùn sí tomijé lójú, níse ni òrò ìròlé n se é ní kàyéfì, ó rò ó títí kò rí i rò, ó sunkún sínú títí tí oorun fi rá a lo.
* * * * * *
“Sé òògùn won yen sì kù?” Adérìnólá tí í se àkóbí Kòsókò Agbábíàká ló n bi àbùrò rè léèrè.
“Ó kù, nígbà tí mo lo níjeèta mó tún bá won ra eyokan dání” Rómólá dá a lóhùn.
“Pé o tún lo sí Alákùko níjeèta?”
Dérìn bi àbúrò rè pèlú ìyàlénu nítórí pé kò lérò pé Ròmòlá tún lè má a lo sí Alákùko pèlú ohun tí ìyá rè fojú rè rí léyìn ìsèlè tó selè níjósí.
Kò sí ohun tó le mú Ròmólá má dé Alákùko, ó féràn baba baba ré bí èmí ni, òun sì ni eyinlójú bàbá àgbà náà, bí bàbá àgbà náà kò bá sì rí i láàrin òsè kan, èèmewàá ni yóò mo pè é lórí ago.
Lílo Ròmòlá sí Alákùko léyìn tí atégùn fé sí ìsèlè ojósí túbò pò ju ti àtèyìnwá lo súgbòn kò lo àlosùn gégé bí ó sé n lo télè mó, kìí se torí Agbábíàká nìkan ni lílo lemólemó rè se lé kèlè kan sí i bíkòse nítórí ti omobìnrin tó jé olóore rè tó n wá tí kò rí.
“Kí n kàn tiè rí i, kí n fi èmi ìmoore hàn sí i lásán ti tó fún mi, sé kò tiè ní má a rò pé mo ya aláìmoore èdá báyìí?” ni ohun tí Ròmólà má a n gbà ládùúrà ní gbogbo ìgbà tó bá ronú nípa “ilédì” rè.
Ròmólá a má a rin agboolé bí i mérin kiri láàrin ilú won lójó mìíràn tó bá lo sí ìlú Alákùko, a sì má a bi àwon tó bá bà pàdé pé bóyá wón mo omobìnrin kan tí kò pupa jù, tí kò dúdú jù, tí kò sì ga jù béè ni kò kúrú jù.
Elòmíràn a mó on lójú, elòmíràn a pòsé won a sì fìbínú kúrò níwájú rè. Bí elòmíràn bà sì setán láti ràn án lówó tí wón béèrè orúko eni náà tí Ròmólá bá sì dáhùn pé “mí ò mo orúko è” ni wón á dáhùn pé “a a tí se Béélò nílórin, àìmoye omobìnrin ní Alákùko, e jé lo wá‘sé se bòdá. Báyìí ní gbogbo ìlàkàkà Ròmólá láti rí “ilédì” rè sé n já sí pàbo.
“Dérìn, Dérìn, dúró ná, ta ni wèrè to gbé síwájú okò e láàárò yen?”
Róláké, ìyàwó Dérìn ló n pariwo bó se n wolé bò láti òde tó lo, kó tiè rí ti kíkí tí Ròmólá kí i rò béè ni kò sì ná-án ní àti kí àwon tó bá nínú ilé.
“Wèrè bi ti báwo?” Dérìn bèèrè pèlú ohùn tútù, Róláké ju àpamówó rè sórí àga, ó pakuru mó Dérin bí pé ó fé so mó on lórùn.
“Hen, wèrè wo le jo lo sóde tó jókòó níwájú pèlú e nínú motor?” Ó tún béèrè pèlú ìgbónára.
“Rólá, o jé má a se sùúrù, sèbí ìyàwó Dìran nìyen.”
“Wèrè wo ló n jé Dìran? Wèrè wo ni kó ní dáa fún t’óún fìyàwó è só e?
Wòó, to bá nífèé ara e ko stop ìranù if not wà a dá’ra e lébi, tí obìnrin kan bà wa n try láti lé mi nídìí erù mi mà á jé kó yé e pé; àlòpa n’ t’atarodo, àjápa n’ t’ewéédú, àgùnpa n’ ti kèké, àgúnpa n’ tiyán, àròpa n’ tigbègìrì, àdínpa n’ t’ejaádín, àwòpa…”
Ròmólá sárá dìde ó gé e mó on lénu ó ní“Háhà, antí” Inú bí Róláké, ó kojú sí Ròmólá ó dá a lóhùn pe, “Sé kò rè é?
Má pè mí o, oníranù ègbón e ni kó o pé ko bè, irú ìró n’borùn.”
Ó yíjú padà sí Dérìn ó lérí pé “wos wo’bí, tí wón bà wá bí e dáa ko lo fún obìnrin lóyún níta, àti ìwo àti ìyá oyún, òrun le ti ma lo bímo yen, oníranù gbogbo” ó pòsé, ó mú àpamówó rè, ó wo yàrá lo.
Òrò di hùn láàrin ègbón àtàbúrò, Dérìn mi orí pèlú èdun okàn, Ròmólá wo ònà enu ònà tìkàtègbin bí kó le kó ìgbájú bo Róláké òun náà mirí kó tó jókòó.
Àánú Dérìn se ara rè, ó rò ó nínú pé àsé òtító ni pé ojà òkùnkùn ni gbogbo eni tí n ná’jà ìfé n ná, sé Róláké tòun fé nìyí shá?
Ní Róláké tó jé pé oníwà tútú bí àdàbà ni lójú ònà, léni tó jé pé béèyàn bomi sí i lénu ibè lèyàn yóò bá a, làwón wá gbéra won sílé tán ló wà d’oko mo òun lówó.
Ó mà se o! Odún kèje rè é táwon tí sègbeyàwó, kò yé, kò pa, béè kò tún fi òun láyà balè, kí alátise òun yá tètè mo àtise ara òun gégé bí i ìmòràn Ròmólá.
* * * * * *
Àdìsá jókòó ní etí àga àgba-n-tara tó wà ní ìta rè, agbè emu wà ní apá òtún rè, ó gbé ihá emu lówó àlàáfíà rè, ó da emu sí ònà òfun, ó gbé ihá kalè ó ní “ògidì lemu i”
Ó tún sé díè sénu kó tó mú orin bonu pé;
“Iró lè n pa, Yorùba ò le è parun,
Iró lè n pa, Yorùba ò le è parun,
Àtélewó la bá’là, a ò meni tó ko o,
Iró lè n pa, Yorùba ò le è parun.”
Bó sé n fi orin dá ara rè lárayá ló n mì lórí ibi tó jókòó sí, èèkan náà ló gbé ojú sókè tó rí Balógun ìlú Alákúkò tó n bò lóòókán, ó sì bèrè sí kì í ní mésàn án mèwàá,
“Balógun, òré mi àtàtà, akonikùnrin tí b’akoni egbé rè lérù, e mó wolè, e mó rora, olówó orí iyìolá, olówó orí Mopélólà, oko Àdùfé tómoge kò lónà tó ní béyìí ò jóko eni kó sì j’álè eni”
“Àdisa, Ààdìsá, Àààdìsá” Balógun pè é bó se dé òdò rè,
“O kú àyésí mi béè o sì kú àlejò mi” Balógún kí Àdìsá
“Àlejò? Sé pé ilé mi lè n bò?” Àdìsá dìde ó bèèrè pèlú ìyàlénu
“Béè ni o, ìwo gan an ni mo wá rí”
“Mo soríire nùn un”
Àdìsà sòrò, ó n sáré fi etí agbádá rè gbon àgbà-n-tara nù
“E fìkàlè si olóyè” ó na owó sí Balógun láti jókòó. Balógun yán apá agbádá rè sótùn-ún, ó yán an sósì, ó yan fa-n-da rìn síwájú kí ó tó fìdí lé orí àga.
“E kúùrìn” Àdìsá kí i léèkan sí i, ó sé emu sínú ihá, ó gbé e fún Balógun tòwòtòwò kí ó tó ké sí Àjoké àti ìyá rè.
“Ìyá Àjoké, Ìyá Àjoké, Àjoké, e jáde wá ní ìhàhín o, eja nla nìwò wá gbé o, àlejò nla la gbà”
Àjoké àti Àdùnni sáré jádé láti inú iyèwù, wón fi orúnkún won méjéèjì kúnlè kí Balógun.
“K’ára ó le o bàbá olóyè”
“E kún, e n lé, e gbéra n’lè”
Bí wón ti dìde lórí ìkúnlè ni Àdúnní wí pé, “e kú àbèwò wa, kín ni ká fún yín ní jíje? Bó se iyán le fé? Àbí okà?
Bó se èwà àdàlú ni àbí sapala?
Èyin e sá ti jè n mò, ke tó séjú pé, gbogbo rè ti pé síwájú yín.”
“O seun aya olá, tìbínú kó béè tenu sì kó, gbogbo ayé ló mò pé àwa gbajúmò è é jeun níta”
“Oúnje è é pò ó jù” Àdìsa fèsì sí òrò Balógun.
“E mó sèyonu” Àjoké àti ìyá rè kí olóyè kúùkàlè léèkan sí i wón sì wolé lo ní tiwon.
Àdìsà fé má a kí Balógun kú ìkàlè ni Balógun fi yè e pè bí kò bá nídìí obìnrin kìí jé kúmólú, òrò kán ló n dun òun lókàn ló jé kí òun to Àdìsá wá.
Èrú ba Àdìsá ó sì lérò pé bóyá omo òun ló yájú sí olóyè tí olóyè sì wá láti wá fi ejó rè sùn.
“Sé Àjoké yájú si yín ni? Sèríà tó bá ye ni ké e dá fún un, e jé n pè é síta” Balógun ní kí Àdìsá fi ara burúkú balè pé Àjoké ò se òun, ó wá so ojú abe níkòó pé níse ni Àjoké wu òun láti fi se aya.
Àdìsá fí owó kan ilè ó fi kan àyà, ó ní “Àyà mi padà wá gbowó ko wá gbomo, e wò ó, olóyè àwòdì òkè mi n rèbarà atégun tá a nídìí kán”
Inú Àdìsá dún nígbà tó gbó ohun tó gbé odidi Balógun ilú won wá sílè rè, sé Àjoké kúkú ti kúrò lómodé lójú Àdìsà, ó ti mo oúnje sè, ó sì ti mo ìtójú ilé se, kín wá ló tún kù?
Okùnrin kankan ò sì wá bèèrè Àjoké nílé rí béè sì ni kò ká á pèlú okùnrin lébàá ògiri rí débi pé Àjoké yóò kò láti fè bàbá olóyè.
Àdìsà kí Àjoké kú oríire lókàn ara rè nítorí pé àwon àgbàlagbà ló mo ìtójú obìnrin se ju àwon òdó langba aláìníkan-an se lo, olóyé è é tún wà se àgbàlagbà làsàn, olóyè pàtàkí tó rí jà je yàtò sí ti búrédì ni.
Àdìsá rò pé b’órèé eni ò bá joba bó o lèèyàn se le je òré oba, bí Àjoké ò bá fé olóyè bó o lòun se fé di àna olóye? A jé pé òun tún kú oríire léèkejì nùn-un, kí Sanjó tó dé láti ibi tó ti lo sin ilè baba rè, òun yóò ti di gbajúmò nínú ìlú Alákùko.
Àdìsá fi Balógun lókàn balè, ó sì mú un dá a lójú pé Àjoké ti di aya rè láti ìgbà náà lo, ó wá jé kó di mímò fún Balógun pé tó bà di èyìn ojó kokànlélógún kí won wá fún èèto ìsíhùn, kí èètò ìdána àti ìgbéyàwó sì tèlé e.
Inú Balógun dùn púpò, ó sì fi tèríntòyàyà ka owó egbèrún márùn ún fún Àdìsá gégé bí i owó ìdákomu.
Àdìsá gbá owó tìdùnnútìdùnnú, ó dà a sí àpò, ó sin Balógun sí ònà, bó se padà dé ó ké sí Àjoké àti ìyá rè láti fi tó won létí…
ÌGBÈYÌN n tèsíwájú...
© RASBAM
2018
Orísun: Rosheedat Bamidele Amusat
0 comments:
Post a Comment