Smiley face

Lọ́jọ́ tí wọn fi Femi Branch jẹ Jagun Asa

Won ni bí a kò ba rí ẹyẹ igun a gbọ́dọ̀ ṣebọ, bí a kò rí ẹyẹ akala a gbọdọ sorò, bí a kò bá ti rí ewé akòko kò sí bá a ti fẹ́ joyè nílẹ̀ yìí.

Ṣùgbọ́n lọjọ tí Timi ìlú Ede, Oba Munirudeen Adesola Lawal, Laminisa I, setan láti fi Femi Branch joyè Jagun Asa tiluu Ede gbogbo èròjà lọ pé.

Laminisa 1 ṣe àlàyé Femi Branch gege bí osere kan eléyìí tí ipa àti akitiyan rẹ kò ṣe fojú parẹ́ lagbo Amuludun ilé Nàìjíríà pátá.

Àìmọye ọrẹ àti ojulumo ni wọn dúró leyin Femi Branch níbi ayẹyẹ ìfinijoyè náà tí gbogbo won sì ń bá yọ fún idanilola àti koriya tí gbogbo ìlú èdè fún un.

Ọmọ ipínlẹ̀ Ogun ni Femi Branch, ẹni tí orúkọ abiso rẹ n jẹ Babafemi Osunkoya.

Ọjọ kẹrìnlá oṣù karùn-ún ọdún 1970 ni wọn bí ní àgbègbè Sagamu.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ilu Eko lọ dàgbà sì, síbè Yunifásítì Obafemi Awolowo tó wà ní ilé Ìfẹ́ lọ ti gboyè nínú iṣe ọnà ati dírámà eré onisẹ.

Kò wá sí ipa tí Femi Branch kò lè kó nínú ìṣe fíìmù àgbéléwò bí ka  kọ ìtàn, dárí ère tàbí kopa gege bí osere.

Yàtò sì eléyìí, Femi tún jé Akewi àpilẹ̀kọ eléyìí tí àwọn ewì rẹ sì fi hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ni arogun àti arojinle.

Iwuye akọsẹmọsẹ onisẹ tíátà, Femi Branch, gẹ́gẹ́ bí Jagun Asa lo wáyé lọjọ kẹwàá osu keta odun 2018 níbi ayẹyẹ ọdún kẹwàá Timi lórí oyè.

Ọba Lamidi Adeyemi, Aláàfin Ọ̀yọ́ wá níkàlẹ̀ lọjọ náà, Oosa Oyo súre fún Femi Branch gẹ́gẹ́ bí wón ṣe gbé adé oyè Jagun Asa lé e lórí.

Oyè a mọ́ rí ọ!

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment