Òkú olówó ọdún kan ni, òkú òtòṣì losu mẹ́fà, òkú ọlọmọ laseesetan.
Toyin Abraham (Toyin Aimakhu tẹ́lẹ̀) ti sin bàbà rẹ, Pastor B.E. Aimakhu, lánàá, 01/03/18, nílùú Ibadan.
Toyin kò lè mú ẹ̀dùn ọkàn rẹ mọ́ra pelu bi omi ṣe ń jabo lójú rẹ nígbà tí eto ìsìn ìkẹyìn náà ń wáyé fún bàbá to bíi lọmọ.
Nínú ọdún to kọjá, ọjọ́ kinni oṣù kẹwàá, ní bàbà Alakada dagbere fàyè ni ẹni odun metadinlogorin (77).
Àdúrà wa ni wí pé kí Olúwa tẹ bàbà náà sì afẹ́fẹ́ rere.
Omo rere yoo gbeyin gbogbo wa oo
ReplyDelete