Smiley face

Báyìí ni Ìyá Dare onigbin ṣe pàdé gómìnà, kositọma rẹ àtijọ́

"Mo má ń sọ fún àwọn ènìyàn wí pé Kositọma mi àtijọ́ ni gomina ṣùgbọ́n wọn kì í gba mi gbọ - Ìyá Dare onigbin ni Owena.

Ó ti pe tí Ìyá Dare tí ń tabin fún Arákùnrin Akeredolu tó jẹ́ gómìnà ipínlẹ̀ Ondo. Ni àwọn àkókò yìí, isẹ agbẹjọro ni Aketi ń ṣe, ọsọọsẹ lo sí má n ra ìgbín lọ sílè fún ìyàwó rẹ to jẹ ọmọ yibo.

Ṣùgbọ́n nígbà tó yá, wọn yan Akeredolu gẹ́gẹ́ bí agbejoro àgbà fún ipínlẹ̀ Ondo. Àti ìgbà náà ni kò ti sì anfaani fún un mọ láti dúró ragbin lójú titi.

Leyin eyi ni Akeredolu tún gbà òye to gaju lọ nínú iṣẹ́ agbejoro, Senior Advocate of Nigeria.

Losu kejì ọdún 2017 ní wọn tún dibo yàn Akeredolu gẹ́gẹ́ bí gómìnà ipínlẹ̀ Ondo. Ìdùnnú ńlá lọ je fún ìyá Dare, gbogbo ìgbà lọ sí má so fún àwọn ènìyàn wí pé Kositọma òun àtijó ni gómìnà ṣùgbọ́n kosi ẹni tó gbà ọ̀rọ̀ rẹ gbọ.

"Inú telifisan nìkan ni mo ti má ń rí Arákùnrin, mi ò sì lérò wí pé mo lè pàdé wọn mọ de ibi wí pé wọn yóò tilẹ rántí ojú mi", ìyá Dare ṣàlàyé.

Ṣùgbọ́n lose to kọjá, àwọn áńgẹ́lì tó ń pín ire sí iwe iranti kan ìyá Dare níbi to ti ń t'àgbín rẹ ni Owena.

Gómìnà pàṣẹ kí wọn dá mọ́tò dúró, ó sọkalẹ láti kí Ìyá Dare. Gómìnà béèrè nípa ẹbí rẹ, o si se ileri lati rán àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́. Yàtò sì èyí, ó tún ṣe iranlowo owó fún ìyá Dare. Báyìí ni ìyá Dare onigbin ṣe di irawo lẹ́yìn to pàdé olóore rẹ.

Nínú ọsẹ tuntun yìí, olóore yóò rántí yín, yóò sì wà ṣe yín loore manigbagbe. Amin

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment