Yorùbá kìí rìn ìrìn ìdọ̀tí. Yorùbá kìí wọ akisa. Yorùbá lónìí ká wọ buba, ká wọ ṣòkòtò, ká wá gbé agbádá le e lórí.
Yorùbá lo ní ká rí ẹni, ká kíni tẹrín-tẹyẹ. Èdè apọnle, nínú èdè Yorùbá ló wà.
Yorùbá kìí jẹ́ orúkọ láì ni ìtumò gidi. Àwọn àgbàlagbà Yorùbá wọn má ṣe òdinwọ̀n bí ènìyàn ṣe gbọn to nípa bí ẹni náà ṣe mọ ọ̀rọ̀ gbọ́ tó tàbí mọ́ọ̀ sọ to. Ìdí ni wí pé, ọgbọ́n ni ohun tí wọn pé ni èdè Yorùbá. Bí ó bá gbọ Yorùbá méjì, ó ti ní ọgbọ́n méjì. Tí ó bá gbọ Yorùbá mẹta, ó ti ní ọgbọ́n mẹta. Yorùbá lè fojú sọ̀rọ̀, fi imú sọ̀rọ̀, fi ahọn sọ̀rọ̀, fi ori sọ̀rọ̀, fi gbogbo ara sọ̀rọ̀ láì yanu sọ̀rọ̀ jáde.
Yorùbá lè sọ pé "bẹẹni" láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò tó sì jẹ wí pé "bẹẹkọ" ni wọn wí. Ẹni wọn ba sọ̀rọ̀ gan-an gan yóò ti wo bí ẹni náà ṣe sẹnu pé "bẹẹni" ni yóò fi mọ̀ wí pé "bẹẹkọ" ni ohun tí ẹni náà ń wí .
Bóyá ẹyin kò tilẹ̀ mọ̀, Ojúlówó ọmọ Yorùbá ni mí. Oluyole Ìbàdàn ni mo ti wá. Ẹyin ńkọ́?
0 comments:
Post a Comment