Ọmọkùnrin kan lórí ayélujára ti gbìyànjú láti fi aṣọ Mikel Obi yidọti. Ọmọkùnrin náà ṣe àlàyé ara rẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ àbúrò bàbà Mikel. Ó ni ara bàbà òun kò yà, inú ìnira lọ wà, kosi sì owó láti fi rán an lọ́wọ́.
Ó ni iranlowo kankan kò wá láti ọ̀dọ̀ Mikel bo se lọ́wọ́ to, ó ni ará ìta nìkan ni Mikel ń ṣe fún.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ká àlàyé rẹ kò tilẹ̀ dúró kí Mikel sọ tẹnu rẹ tí wọn fi bẹ̀rẹ̀ si ni bú u. Ẹni kan ni, "a mọ irú wọn, a dáa níta má dáa nílé níwọ̀n" .
Oníkálukú wọn bẹ̀rẹ̀ si ni sọ ohun tó wù wọn. Ṣùgbọ́n mo ni ìrírí kan tó jọ irú iṣẹlẹ yìí. Mo ní ebi kan lókè òkun eléyìí to má ń ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bi àgbàrá rẹ tí ṣe mọ. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn rẹ a má sọ káàkiri wí pé ahun ni kii se fún ẹnikẹ́ni.
Tí mi o bá mọ wí pé ẹni náà ń ṣe fún wọn, oseese kí n gba wọn gbọ wí pé ahun ni ẹni náà ní tòótọ́. Ohun tó ṣe fún wọn, wọn kò ni sọ ọ. Ohun tí ò ṣe ni wọn o má gbé kiri.
0 comments:
Post a Comment