Smiley face

Ìkà tí ẹbi Abiola ṣe fún MKO ju ti IBB àti Abacha lọ

Ìròyìn tí kárí ayé wí pé wọn ti fi olóògbé Moshood Kashimawo Olawale Abiola jẹ òye idanilọla orile-ede Nàìjíríà tó gaju lọ, GCFR.

Ṣùgbọ́n ẹ̀dùn ọkàn ńlá lo má ń jẹ fún mi nígbà tí àwọn ènìyàn bá ṣe ìrántí Abiola to sì jẹ wí pé igbe ayé rẹ gẹ́gẹ́ bí oloselu nìkan ni wọn rántí pàápàá julọ eto idibo June 12.

Abiola tí ṣe asejere gẹ́gẹ́ bí olokoowo ńlá, eléyìí gan-an lo fún ni àǹfààní láti raye nínú òṣèlú ilẹ̀ wa.

Àìmọye àwọn oniroyin ni wọn ti ṣe àgbékalẹ̀ ìṣe ìròyìn tó jinlẹ nípa bí June 12 ṣe bọ mọ Abiola lọ́wọ́.

A kò rẹni to sọ nípa bí okoowo rẹ ṣe parun lẹ́yìn ikú rẹ.

Ilé ìṣe ìròyìn Premium Times tilẹ ṣe àlàyé bí àwọn àgbà oloye ẹgbẹ́ SDP ṣe dalẹ ọkọ Kudirat lẹ́yìn tí wọn ju sẹwọn tan.

Títí di àkókò yii, ko sì àlàyé nípa bí àwọn ẹbí Abiola ṣe jẹ́ dúkìá rẹ rún tí wọn sì sọ Abiola di olówó àná.

Asa ilé adúláwò ni ogún pipin. Ṣùgbọ́n ojú kòkòrò, ẹ̀ta inú, adanikanjẹ, ìwà olè jíjà ni wọn fi ń ṣe eto ogún pípín eléyìí sì ń fà ifaseyin pupọ fún ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Báwo ni kọ bá ṣe dùn tó ti àwọn ilé isẹ Abiola ṣi wà títí di òní.

Kí àwọn ayé to mọ ẹni tí ń jẹ Dangote ni orúkọ Abiola kò bá ti wá nípò aláwọ̀ dúdú tó ní owó 💵 ju lọ lagbaye to ba jẹ wí pé wọn tọ́jú dúkìá rẹ dáadáa.

Sugbon ojú kòkòrò, imọ tara ẹni nìkan àti ìwà ajẹtan àwa èèyàn dúdú kò jẹ.

Àwọn ileese Abiola kò bá ti pọ̀ sii ni ìlọ́po-ìlọ́po, àìmọye ọ̀dọ́ ni yóò tún risẹ ṣe, eto ọrọ ajé ilé wa yóò tún lọ sókè sii tó bá jẹ́ wí pé ojú kan soso ni àwọn dúkìá yìí wà tí wọn sì ń ṣe àbójútó rẹ dáadáa pẹ̀lú òtítọ́ inú kan. Gbogbo ẹbí rẹ ni kọ bá padà jẹ ajesejuku, ohun ìwúrí ńlá ni yóò sì jẹ fún wọn.

Ṣùgbọ́n kété tí Abiola kú ní àwọn ẹbí rẹ tí ń já sí ogún bàbà wọn. Àìmọye ìgbà ni wọn tilè gbé Kola Abiola to jẹ àkọ́bí MKO lọ sí ilé ẹjọ́ látàrí wí pé ó fẹ́ yàn àwọn àbúrò rẹ jẹ.

Akiyesi yìí kì ń ṣe nípa ẹbí MKO nìkan, bákan náà lọ ṣe rí káàkiri ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Ọjọ ti olówó bá ti kú ní ọlá àti dúkìá rẹ wọmi pátápátá eléyìí tí kò rí bẹ́ẹ̀ pelu awon aláwọ̀ funfun.

Igba ti bàbà mi kú, orisirisi àwọn ènìyàn ní wón wá, wọn ní ara mọ̀lẹ́bí ni àwọn jẹ́. Àwọn náà fẹ gba ẹtọ wọn. Ẹnikẹ́ni kò sọ nípa bí eto ẹ̀kọ́ wá kò ṣe ní dúró.

Ẹnikẹ́ni kò tilẹ dámọ̀ràn eto fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tí olóògbé fi silẹ lọ.

Báwo ni ìyá kò ṣe ní je wọn, báwo ni orúkọ olóògbé ko ṣe ni parun? Àwọn nǹkan wọ̀nyí kò bá wọn.

Kò sí èyí tí mo mọ nínú àwọn tí wọn pé ara wọn ní molebi ṣáájú àkókò náà. Bákan náà ni kọ sí èyí tí mo rí mọ nínú wọn lẹ́yìn tí wọn gba ẹtọ wọn eléyìí ti wọn bèrè fún.

Kosi iyì tàbí ẹyẹ tí wọn lé ra fún orúkọ MKO tó lè dabi èyí tí okoowo rẹ yóò fún tó bá jẹ́ wí pé wọn ṣe ìtọ́jú àwọn dúkìá rẹ dáadáa.

Gbogbo àwọn ènìyàn ní wón wo IBB àti Abacha gẹ́gẹ́ bí ọta Abiola, ṣùgbọ́n mo fi dáyin lójú wí pé ijamba tí àwọn ẹbí rẹ ṣe ju ti àwọn méjèèjì.

A kò lè sọ, bóyá jíjẹ aare orileede kò sì nínú kádàrá MKO to jẹ wí pé Olawale ń tako akunleyan lásán ni. IBB kan lè jẹ sababi láti rí wí pé MKO kò gbà ju òun ti kádàrá fún lọ. Ta lo lè sọ?

Ǹjẹ́ àwa lè sọ wí pé èyí burú ju bí àwọn ẹbí rẹ ṣe jẹ́  dúkìá àti ọlá Abiola rún, ohun tó sise fún  ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ. Ohun tí MKO jìyà fún pare lai ṣe wí pé kò fi ọmọ sáyé lọ.

Kí Edumare fi ọ̀run kẹ Kashimawo bàbà Kola

Olayemi Olatilewa
yemoford@gmail.com

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment