Àṣírí tí lu jáde báyìí wí pé wọn ti fà orúkọ Bukola Sàràkí kúrò nínú esun ìdaràn idigunjale tó wáyé nílùú Ọffa níbi tí àìmọye èmi ti ṣòfò.
Àwọn ọ̀daràn afurasi tí wọn mú látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ idigunjale àwọn banki nílùú Offa ni wọn jẹwọ wí pé, ọmọ jagidijagan Bukola Sàràkí àti Gomina Fatai Hamed ipínlẹ̀ Kwara ni àwọn ọn se ṣáájú àkókò náà.
Àti wí pé gbogbo èròjà tí àwọn ni lo jẹ ẹyi tí wọn fún àwọn ni akoko ìdìbò.
Àwọn igara ọlọ́ṣà náà ṣe àlàyé wí pé, Sàràkí kò mọ̀ nípa idigunjale tó wáyé náà. Ona atijẹ lásán ni àwọn wá kiri.
Lẹ́yìn èyí ni ile ise ọlọ́pàá àpapọ̀ ilé Nàìjíríà 🇳🇬 fi ìwé pé Ààrẹ ilẹ̀ ìgbìmọ̀ asofin àgbà Abuja, Bukola Sàràkí láti wá sọ tẹnu rẹ lórí ẹ̀sùn naa.
Àìmọye awuyewuye lo suyọ lẹ́yìn èyí eléyìí tí àwọn àgbààgbà olóṣèlú kan bẹ̀rẹ̀ si ni forí-korí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ní àkókò yìí kan náà ni igbekeji aare ilẹ̀ Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo ṣe ìpàdé idakonko pelu ọ̀gá àgbà àwọn ọlọ́pàá.
Leyin ìpàdé yìí ni oga ọlọ́pàá kéde wí pé kìí se dandan mọ kí Sàràkí yọjú sì àgọ́ ọlọ́pàá. Wọn ni Sàràkí lè jáwèé kékeré kan kò fi kò leta ranse sì àwọn lórí òun tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Báyìí gẹlẹ ni Sàràkí ṣe dá wọn lóhùn. Ó sì ṣàlàyé sínú lẹta náà wí pé irọ́ lásán ni gbogbo ẹ̀sùn náà.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé to lu síta, ṣáájú kí Sàràkí tó lọ sí Saudi Arabia lásìkò awẹ Ramadan ni wọn ti yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ naa pátápátá. Eraser to shaprapra ni wọn si fi pa orúkọ Sàràkí àti Gómìnà Fatai rẹ nínú faili ẹ̀sùn ìdaràn náà eléyìí tí wọn ṣe lókùú òru.
Jù gbogbo rẹ lọ, àwọn ọ̀daràn afurasi tí wọn mú náà sì wà ní àtìmọ́lé eléyìí tí ilé ìṣe ọlọ́pàá kò ti kede àkókò tí wọn yóò fojú bale ẹjọ́.
0 comments:
Post a Comment