Smiley face

Iporuuru ọkàn: Ajakalẹ àrùn tí ń yọ Nigeria lẹ́nu

Tí a bá ń parọ fún ara wa ni a má fi ọ̀rọ̀ sì abẹ ahọn sọ. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ sì ni wi pe nǹkan burú síi ní fún orile-ede Nàìjíríà.

Àpẹẹrẹ wí pé ọrọ aje ń Nàìjíríà rẹyìn ni iroyin àwọn ènìyàn tí wọn gba èmi ara wọn látàrí ìpòrúuru ọkàn eléyìí to tí wá gbajugbaja lásìkò yìí. 

Ti a ba wo ohun tó fàá bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbẹ̀mí ara wọn, púpò nínú rẹ lo rọmọ ọrọ̀ ajé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé àwọn ìdí mìíràn náà ṣokùnfà rẹ pẹ̀lú.

Kò sí ohun tó já ní láyà ju bí àìlówó lọ́wọ́. Ibanujẹ ńlá àti ìpòrúuru ọkàn sí ní fún ẹni ogójì ọdún tí kò lè dá gbọ bùkátà ara rẹ débi wí pé yóò rán ebi rẹ lówó.

Pupo àwọn ènìyàn tí wọn pa ara wọn ní kìí se wí pé àìrí owó ra ọkọ̀ mẹ̀sí ọlọyẹ́ ni wọn fi gbẹ̀mí ara wọn bí kò se ibanujẹ ọkàn eléyìí to waye látàrí wí pé wọ́n kò ni àǹfààní láti gbé ilé ayé bí àwọn ènìyàn tó kú.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ World Health Organization (WHO) ṣe ṣe àfihàn abaje wọn, wọn fi ye wa wi pe iye àwọn ọmọ Nàìjíríà tí iporuuru ọkàn ń bájà jẹ 7,079,815 eleyii to din díè ni ida mẹrin nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn onka apapo àwọn ọmọ Nàìjíríà. Ẹ lè rí alaye lori àte isale yìí

https://www.wellbeingwomen.org/depression-in-nigeria

Ẹ lọ míì gba èmi ara rẹ látàrí wí pé ko ri owo ilé rẹ san.
Òpó lọ ń ṣe àìsàn tí wọn kò sì rówó toju ara rẹ.
Àwọn ènìyàn n ṣòwò wọn rí ère jẹ
Aimoye tó ń wasẹ tí kò risẹ lo ti sọ ìrètí nù pàtápàtá.

Kosi wàásù tó lè ṣe ìwòsàn fún ẹni tí ebi ń pa ayafi tó bá rí oúnjẹ. Àwọn Yorùbá sì ni ti oúnjẹ bá ti kúrò nínú ìṣẹ́, ìṣẹ́ buse.

Olayemi Olatilewa
olayemioniroyin@gmail.com

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment