Hubert Ogunde |
Kòsí bí a ṣe fẹ kí Ìbàdàn láì mẹ́nu ba àrùn Ìbàdàn; sebí wọ́n ní ìjàgboro làrùn Ibadan. Bawo ni eniyan o ṣe ki Ẹ̀gbá ọmọ Lisabi lai mẹ́nu ba olúmọ òkè rìbìtì. Kosi ọna ti a le gba sọ nipa iṣẹ tiata Nigeria tàbí ilẹ̀ Afíríkà ti ènìyàn yóò si fojú pa Hubert Ogunde rẹ́.
Gẹgẹ bí Ebun Clerk (1979) ṣe gbé kalẹ, Ó ní Hubert Ogunde ni a lè pè ní ipìlẹ̀ eré tíátà atì sinimá èdè Yorùbá. Tàbí ẹni àkọ̀kọ́ tí yóò ṣe àgbékalẹ̀ eré oníṣe eléyìí tó yàtò si èyí ti a n ri níbi awọn ọdún ìbílẹ̀ wa gbogbo. Níbí yìí náà ló ti tako bi Ulli Beier ṣe gbé ògo ìdásílẹ̀ eré títíà fún Dúŕo Ládiípò.
Contrary to previous statements by theatre historians, Duro Ladiipo was not “the first dramtist of Yoruba theatre to whom oral tradition mattered very much’, nor was he the first to explore ‘the wealth of Yorùbá myths,legends, and history’ and her prolific poetry, music and dance’.
Ìwádìí tun fihàn wí pé Ogunde tí ń ṣe àwọn
eré tíátà eléyìí tó jẹ́ àwọn ìtàn tó fàyọ láti inú bibeli ni
nnkan bi ọdun 1943 kí ó tó wa da ẹgbẹ ti ẹ sílẹ̀ ni odun 1945.
Ní ọdún 1944 ni o ṣe àgbékalẹ̀ àwọn àkọ́já
ewé eré tíátà rẹ̀ eléyìí ti o pè ní The Garden of Eden ati Throne
of God. Won ṣe àfihàn àwọn ere yii ni Glover Memorial Hall to wa ni
ilu Eko lọjọ Kejila, osu kefa. Lara awon onworan ọjọ́ naa ni Ogbeni Nnadi
Azikiwe.
0 comments:
Post a Comment