Ǹjẹ́ ẹ ṣe àkíyèsí wí pé ẹni oòrùn ara (Body Odour)?
Ẹ wá ọsan wẹẹrẹ eleyii ti wọn tun pé ní ọṣàn wẹ́wẹ́ (lemon). Ẹ gee si méjì, kí ẹ sì fi fọ abiya yín tí ó bá ti ku bí iseju márùn-ún sí mẹ́wàá tí ẹ fẹ́ lọ wẹ.
Ọsan wẹ́wẹ́ tí ẹ gé yìí nìkan ni ẹ má fi fọ abiya yín méjèèjì.
Tí ẹ bá ti fọ ọ tán, ẹ fi silẹ bẹẹ fún bí ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá.
Lẹ́yìn èyí, ẹ lè lọ wẹ̀ ìwẹ̀ àárọ̀ yín kí ẹ tó jáde nílé.
Tí ẹ bá ń ṣe eléyìí nígbà gbogbo , saka ni ara yín yóò má dá lai si oòrùn ara kankan tàbí ohun tí wọn pé ní body odour.
Tí ẹ bá ń ṣe eléyìí, ẹ kò nílò pafiimu kankan nítorí òórùn kankan kò ní jẹyọ láti ara yín mọ.
Mo dúpẹ́ fún àkókò yín tí ẹ fi ka àlàyé yìí.
Olayemi Olatilewa
0 comments:
Post a Comment